Ẹ̀sùn Walter Onnoghen : PDP ní Buhari fẹ́ da Nàìjíríà rú!

Onidajọ Walter Onnoghen Image copyright The Guardian
Àkọlé àwòrán Ọpọ ọrọ lo ti jade lori iroyin naa.

Awọn eekan lawujọ ti bẹrẹ si ni sọrọ lati tako igbesẹ pe Adajọ Agba lorilẹede Naijiria, Walter Onnoghen yoo fi oju ba ile ẹjọ lori ẹsun pe ko kede awọn dukia rẹ kan.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubakar to tun jẹ oludije ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ti kilọ fun aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC pe ki wọn maṣe ko orilẹede Naijiria si inu wahala pẹlu ohun to pe ni 'imura kankan wọn lati fi tipatipa yọ Onidajọ Walter Onnoghen.'

Falz f'ohùn lẹ̀ fún PDP, APC, MURIC, àwọn ọmọ Yahoo

Ọlọ́pàá f'aṣọ bójú gbé Dino kúrò nílé ìwòsàn

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMoses Melaye: Dino Melaye sùn ìta gbangba mọ́jú níléesẹ́ DSS

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ abamẹta, Atiku Abubakar ni igbimọ lati yọ Onidajọ Onnoghen kuro nipo wa lara awọn igbimọ pọ kọju ija si ẹka iṣedajọ paapaa pẹlu ipa ti yoo ko ninu abajade esi idibo ọdun 2019.

Bakan naa, minisita fun irinna ofurufu lorilẹede Naijiria nigba kan ri, Fẹmi Fani-Kayọde pẹluko gbẹyin ni ara ọna ti o n fihan pe o ṣeeṣe ki aarẹ Buhari maa fẹ fi ipo silẹ bi o ba fidirẹmi ninu ibo ọdun 2019 ni igbesẹ naa.

Image copyright NATIONAL JUDICIAL COUNCIL
Àkọlé àwòrán Ẹsun aiṣe ootọ nipa awọn dukia ti adajọ agba naa ni lo ko ba adajọ agba naa

"Deji Adeyanju wa ni ahamọ lori ẹsun ipaniyan. Dino Melaye wa lahamọ lori ẹsun igbimọ fẹ paniyan, Doyin Okupe wa lahamọ lori ẹsun ikowojẹ.

"Sambo Dasuki wa lahamọ lori ẹsun ikowojẹ. Ibrahim El-Zakzaky wa lahamọ fun ẹsun ipaniyan.

Ni bayii, Adajọ Agba Naijiria ni wọn tun ti fi kun un bayii. Eto nla ni eyi ti wọn ti kọ ni akọtan."

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu alatako to lamilaaka julọ lorilẹede Naijiria, PDP pẹlu n fi ẹsun kan ijọba apapọ pe sugbọn ati da orilẹede Naijiria ru ni wọn n da.

Amọṣa, alaga igbimọ olugbaninimọran fun aarẹ lori ọrọ iwa ibajẹ, Ọjọgbọn Itse Sagay (SAN) ni igbesẹ ati fi Adajọ Agba Onnoghen jofin fihan pe ko si ẹni kan to ga ju ofin lọ ni.

O ni bi o ti lẹ jẹ pe iroyin naa bani ninu jẹ gidi gan ni, sibẹ o n fihan ni pe ofin ti n jọba lorilẹede Naijiria.

Iroyin latọdọ awọn iwe iroyin lorilẹede Naijiria n fi ye ni pe ile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ibajẹ ati aṣemaṣe awọn to di ipo ilu mu, CCT ti gbe igbimọ ti yoo gbọ ẹjọ naa kalẹ.

Igbimọ ẹlẹni mẹta eyi ti alaga ileẹjọ CCT yoo lewaju fun, ti wa nikalẹ bayii lati gbọ ẹsun naa ti yoo bẹrẹ ni Ọjọ Aje.

CCT: Adájọ́ àgbà Naijiria, Walter Onnoghen yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ìwà aṣemáṣe

Image copyright National Judicial Co

Adajọ Agba Nigeria, Nkanu Onnoghen yòó fojú ba ilé ẹjọ́ to ń gbọ́ ẹ̀sùn iwa ibajẹ laarin awọn to di ipo ilu mu (CCT) ni ọjọ Aje, agbenuso fun ile ẹjọ naa, Ibraheem Al-Hassan lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.

Ninu atẹjade kan ti o fi ṣọwọ ni ọjọ Abamẹta, Al-Hassan ni ẹsun aiṣe ootọ nipa awọn dukia ti adajọ agba naa ni lo ko baa.

Ajọ CCT ni ọjọ ẹti ni awọn fi iwe ẹsun alabala mẹfa naa ṣọwọ si alaga ile ẹjọ CCT, ti wọn si ti fi iwe ipẹjọ ṣọwọ si adajọ agba naa. Gbogbo ẹsun mẹfẹẹfa lo da lori aisẹ ootọ nipa awọn dukia to ni.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Awọn adajọ mẹta ni ti Adajọ Danladi Y. Umar yoo ṣe alaga fun ni yoo ṣe igbẹjọ naa ni oriki uke ẹjọ naa to wa ni Jabi Daki Biyu, Soloman Lar Way, Abuja, ni agogo mẹwaa.

Ọdun 1989 ni Onnogben di adajọ ni Ipinlẹ Cross River ti o si di adajọ ile ẹjọ to ga julọ ni NIgeria ni ọdun 2005.

Oṣun kọkanla, ọdun 2016 ni aarẹ Muhammadu Buhari yan an gẹgẹ bii adajọ agba fun orilẹede yii ti yiyan rẹ si fi idi mulẹ ni oṣu kẹta ọdun 2017.