CCT: Adájọ́ àgbà Onnoghen yóò jẹ́jọ́ lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù kínní

Èrò àwọn ènìyàn sọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ẹ̀sùn Onnoghen Image copyright @todayng, @SERAPNigeria
Àkọlé àwòrán Èrò àwọn ènìyàn sọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ẹ̀sùn Onnoghen

Ọtọtọ ni ero awọn eekan lawujọ atawọn ọmọ Naijiria nipa iroyin to wa lode lori ẹsun pe adajọ̀ agba orilẹede yii ko kede awọn dukia rẹ kan.

Ninu atẹjade kan ti o fi ṣọwọ ni ọjọ Abamẹta, Al-Hassan ni ẹsun aiṣe ootọ nipa awọn dukia ti adajọ agba naa ni lo ko ba a.

Èrò àwọn ènìyàn sọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ẹ̀sùn Onnoghen

‘Yorùbá, ẹ dìbò fún Buhari láti bu ọlá fún M.K.O Abiola’

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEko Akete yóò gbàlejò BBC Yoruba

Ajọ CCT ni ọjọ ẹti ni awọn fi iwe ẹsun alabala mẹfa naa ṣọwọ si alaga ile ẹjọ CCT, ti wọn si ti fi iwe ipẹjọ ṣọwọ si adajọ agba naa.

Gbogbo ẹsun mẹfẹẹfa lo da lori aise ootọ nipa awọn dukia to ni.

Image copyright OAL.LAW
Àkọlé àwòrán Adájọ́ àgbà Onnoghen

Ẹwẹ, ajọ tó n polongo fun akoyawọ ninu iṣejọba Naijiria, SERAP fi sita loju opo Twitter won pe ẹsun ti wọn fi kan Adajọ Agba orilẹede Naijiria, Walter Onnoghen fẹ da bi eyi ti ilana ofin rẹ n mi lẹsẹ eyi si n da yẹyẹẹ ẹka idajọ ni Naijiria silẹ ni. Eyi sile ṣakoba fun ogun ti iṣejọba n gbe ti iwa jẹgudujẹra wọn si gbudọ dawọ rẹ duro ni kiakia.

Loju opo SERAP yii kan naa ni awọn ọmọ Naijiria ti sọ ọ di rọngbọndan.

David dahun pe "ki lo n jẹ pe ofin n mi lẹsẹ ninu keeyan ṣe afihan dukia rẹ, ofin to na tan ni. Ki ẹ ma gbe lẹyin oṣelu.

JUPOCE ni tirẹ gbe lẹyin SERAP, o wi pe fun igba akọkọ oun ro pe wọn sọ ootọ ninu idajọ wọn ati jija fun awọn ọmọ Naijiria.

Chikaritto sọ pe "o pani lẹrin pe ẹgbẹ kan ti ko dara le ijọba to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra gan lo n fi imọran lọ pe ki wọn dawọ igbogun ti iwa jgudujẹra duro. Iwa agabagebe niyii.

Segun Ologe sọ pe wọn ko le dede gbe onimọ ofin kankan lọ ile ẹjọ (to fi mọ CCT) ayafi bi ẹjọ naa ba ti kọkọ de iwaju ajọ to n ri si ọrọ ofin nitorinaa, igbesẹ yii ko tọna.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Twitter ló gbà mí lọ́wọ́ ikú'