Àwọn òṣèré, olórin Yorùbá gbàdúrà fún MC Oluomo

Ronke Oshodi Oke gbadura fun imularada MC Oluomo Image copyright Ronkeoshodioke, iyaboojo
Àkọlé àwòrán Ronke Oshodi Oke gbadura fun imularada MC Oluomo

Àwọn gbajugbaja òṣèré ati olórin Yorùbá lorilẹede Naijiria n ṣe asúgbàá oloye ẹgbẹ awọn awakọ Naijiria, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluomo.

MC Oluomo fara pa nibi ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC to waye nipinlẹ Eko lọjọ diẹ sẹyin o si ti wa nile iwosan nipinlẹ Eko lati igba naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe o ṣeeṣe ki wọn gbe MC Oluọmọ lọ si oke okun lati lọ tẹsiwaju itọju rẹ ṣugbọn lẹyin rẹ ni omii jade pe o n peleke sii ni.

Nigba ti awọn oṣere gbọ eyi, wọn brẹ si ni fi ọrọ ikini ati adura ranṣẹ si oloye ẹgbẹ NURTW naa.

Awọn oṣerebinrin bii Iyabo Ojo, Ronke Oshodi Oke loju opo instagram wọn gbadura pe ki MC Oluomo tete dara ya.

Ẹwẹ, loju opo instagram Ronke Oshodi Oke yii kan naa, awọn ọmọ Naijiria fesi si adura rẹ.

Atawọn to n ti Oluomo lẹyin atawọn to jẹ ololufẹ Ronke ṣugbọn ti wọn ni o ja awọn kulẹ nitori wọn ni "o ngbe lẹyin janduku oloṣelu to ti gba ẹmi ọpọ".

O fi han loju opo instagram rẹ pe kii ṣe nigba to rẹ ẹ nikan ni Ronke foju han gẹgẹ bi ọrẹ rẹ, ojo ti n pa igun wọn bọ ọjọ ti pẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEko Akete yóò gbàlejò BBC Yoruba