'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oduduwa Alphabet: Òmìnira èdè ti dé fún Port Novo báyìí

Ìdalu ni ìṣèlú, ibi gbogbo la ti n kadiyẹ alẹ́ ni ọrọ ede jẹ́.

Alifabẹẹti to jẹ ohùn Oduduwa ree ti wọn fi n kọ awọn ọmọ ni Port Novo ni eyi ti wọn fi gba pé èdè yoruba kò fi ni parun.

Oloye Tolulaṣẹ ni ilu Ajaṣẹ ṣalaye pataki ki iran Yoruba ni alifabẹẹti ara wọn lasiko yii ki awọn ọmọ to wa lẹyin odi lè mọ ede baba nla wọn daadaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O mẹnuba ominira ninu ede ti ko si fun iran Yoruba ni Port Novo tẹlẹ ṣugbọn ti ayipada ti de ba bayii.

Ohùn Yoruba lo yẹ ki a fi maa kọ ede Yoruba silẹ ni imọran to ni fun iran to mbọ.

Ni ipari Oloye Tolulaṣẹ sọrọ lori ayipada to ti de ba ede Yoruba lẹnu awọn ọmọ ni Port Novo.