Walter Onnoghen: Irọ́ ni pé EFCC fi páńpẹ́ ọba mú mi

EFCC ati Walter Onnoghen Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Àjọ EFCC ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìròyìn tó ní pé àjọ náà fi páńpẹ́ ọba mú Adájọ́ Àgbà Nàíjíríà, Walter Onnoghen.

Adajọ Agba lorilẹ-ede Naijiria, Walter Onnoghen ti ni ko si otitọ ninu iroyin to n kaakiri wi pe ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC fi panpẹ ọba mu òun.

Walter Onnoghen bu ẹnu ẹtẹ lu iroyin naa gba ẹnu oluranlọwọ pataki fun un lori ọrọ to jẹ mọ eto iroyin, Arakunrin Awassam Bassey, ti o si pe e ni iroyin ẹlẹjẹ.

Minisita tẹlẹri fun ọrọ irina ofurufu, Oloye Femi-Fani Kayode lo kọkọ gbe iroyin ẹlẹjẹ naa jade pe Ajọ EFCC ti yabo ile Adajọ Agba Walter Onnoghen to wa ni Abuja to jẹ olu ilu orilẹede Naijiria.

Bakan naa saaju ni ajọ EFCC ti fi atẹjade si ita wi pe irọ lasan ni iroyin wi pe awọn fi panpẹ ọba mu Adajọ Agba, Walter Onnoghen.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOduduwa Alphabet: òmìnira èdè ti dé fún Port Novo báyìí