Òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: A ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì fún ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta

NLC-AJIMOBI Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Àjọ òsìsẹ́ náà ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ kò láti mú àdéhùn se lórí àwọn ohun tí àwọn ń béèrè lọ́wọ́ ìjọba.

Awọn osisẹ ijọba ni ipinlẹ Ọyọ ti gunle iyansẹlodi oni ikilo ọlọjọ meta lati beere fun ohun ti wọn fẹ lọwọ ijọba.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ to n duna-dura lorukọ awọn oṣiṣẹ, Public Service Joint Negotiation Council, fi sita lati ọwọ Akinfenwa Olabọde, ṣalaye wi pe ijọba kọ lati dahun si awọn ẹtọ ti awọn beere fun ninu iwe ti awọn kọ si ijọba ni Ọjọ Keje, Osu Kini, ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWoli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

Ninu ọrọ wọn, Ọjọru ni iyansẹlodi naa yoo beere ti ijọba ko ba wa wọrọkọ fi sada lori awọn ohun ti awọn osisẹ ijọba naa n beere fun lẹyin ikilọ ọlọjọ meje ti awọn fun wọn, to si pari ni Ọjọ Isẹgun, ọsẹ yii.

Ẹgbẹ naa wa parọwa si gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiola Ajimobi lati dahun si ọrọ to jọmọ igbaye gbadun awọn osisẹ ni ipinlẹ naa.