Ṣé o lè dìbò fún olùdíje obìnrin? #BBCNigeria2019
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Iṣẹ́ ìlú yàts gidigid si iṣẹ́ ilé ni igbagbọ ẹlomii.

BBC Yorùbá jade kaakiri lọ wadii boya awọn obinrin funra wọn ti ṣetan lati gbe obinrin ẹgbẹ wọn sori aleefa iṣejọba alagbada.

Eyi wu mi ti ko wu ọ lo jẹ ki èrò wọn kó dọgba si idahun ibeere naa.

Awọn kan gba pe ko le rọrun rara lati fiṣẹ ilé bii ina dida kuniṣẹ ìlú ati pe Olorun ti gbe iṣẹ adari fawọn ọkunrin lati ibẹrẹ.

Ohun to kọiwaju sẹni kan, ẹyin lo kọ si ẹlomii bi ilu gangan, awọn mii ni obinrin lo ni ile, obinrin naa lo ni ìlú ni eyi to fihan pé ko si nkan ti ọkunrin n ṣe tobinrin ko le ṣe.

Wọn fẹnuko pe ti ọpọlọ obinrin naa ba pe, ko si ohun to buru ninu gbigbe agabra adari le won lọwọ paapaa lasiko yii to dabi pé awọn ọkunrin ti kuna ninu iṣẹ ìlú ni NAijiria loju ti wọn.