Mọ̀ nípa adelé adájọ́ àgbà tuntun, Ibrahim Tanko Muhammed

Ibrahim Tanko Muhammed Image copyright AsoRockVilla
Àkọlé àwòrán Ibrahim Tanko Muhammed

Aarẹ Buhari ṣẹṣẹ yan adajọ agba tuntun lati dele gẹgẹ bi adajọ agba dipo adajọ Walter Onnoghen to ti jẹ adajọ orilẹede Naijiria.

Igbesẹ yii jẹ jade latari ẹsun ti wọn fi kan adajọ Walter pe ko kede awọn dukia rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn to di ipo nla mu lawujọ.

Ẹwẹ, aarẹ Buhari ti yan adajọ tuntun Ibrahim Tanko Muhammed lati jẹ adele fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Wọnyii ni awọn ipo ti adajọ tanko ti di mu ri lorilẹede Naijiria ati awọn koko ọ̀rọ̀ miiran ti o le mọ nipa rẹ̀.

Image copyright AsoRockVilla
Àkọlé àwòrán Ibrahim Tanko Muhammed
  • Adajọ Tanko Muhammed di adajọ agba ile ẹjọ giga ilu Abuja ni ọdun 1989 titi di 1991 ti iṣẹ tun gbe e lọ si ipinlẹ Bauchi.
  • Ọdun mẹtala lo fi ṣe eyi lẹyin naa ni wọn yan an si ara awọn adajọ agba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọdun 1993.
  • Adajọ agba ile ẹjọ to ga ju lọ lorilede Naijiria ni Ọgbẹni Tanko.
  • Ọdun 1982 ni Tanko bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi amofin lẹyin ti wọn gba a wọle sinu iṣẹ naa lọdun 1981 eyi tii ṣe ọdun kan naa to kẹkọọ nile iwe ikọṣẹmọṣẹ ofin.
  • Adajọ kẹkọọ ile iwe giga fasiti ja ni Fasiti Ahmadu Bello, Zaria. Lẹyin naa lo tun gba oye ipele keji (Masters) ati ipele ikẹta (Ph. D) lati ile iwe giga fasiti kan naa.
  • Ọjọ kọkanlelọgbọ́n oṣu kejila ọdun 1953 ni wọn bi adajọ Ibrahim Tanko Muhammed ni ilu Doguwa, ijọba ibilẹ Giade ni ipinlẹ Bauchi.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.