#BBCGovDebate: Sanwo-Olu, Jimi Agbaje yọ kúrò nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ìtagbangba BBC ní Eko

Jimi Agbaje ati Babajide Sanwo-Olu
Àkọlé àwòrán Gbogbo ìgbésẹ̀ ni BBC News Yorùbá gbé láti ríi pé Babajide Sanwo-Olu ti APC ati Jimi Agbaje ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láti wá ṣùgbọ́n wọ́n ní àwọn kò leè wá

Lẹ́yin-o-rẹyin, eto ijiroro itagbangba ileeṣẹ BBC yoo waye ni ọjọ abamẹta ni ipinlẹ Eko.

Awọn oludije marun ni o yẹ ko kopa ninu eto ọhun ṣugbọn awọn oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ aṣia ẹbẹ oṣelu APC, Babajide Sanwo-olu ati ẹgbẹ oṣelu PDP Jimi Agbaje ko ni kopa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Day 21: Wo bí Dapo Abiodun ṣe rìn ín tó di olùdíje APC l'Ogun #BBCNigeria2019

Atiku, Saraki, ẹgbẹ́ àwọn agbẹ́jọ́rò ta ko Buhari nípa Onnoghen

Mọ̀ nípa adelé adájọ́ àgbà tuntun, Ibrahim Tanko Muhammed

Ezekwesili: Irọ́ gbáà ni ẹgbẹ́ òṣèlú ACPN ń pa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.

Gbogbo ọna to yẹ ni yiyẹ ni ileeṣẹ BBC gba lati rii pe awọn mejeeji yii kopa ṣugbọn lẹyin-o-rẹyin awọn mejeeji yii ni awọn ko ni lee kopa ninu ijiroro itagbangba naa.

Amọṣa, awọn oludije ti yoo kopa bayii ni Babatunde Gbadamọṣi ti ẹgbẹ oṣelu ADP, Ọmọlara Adesanya fun ẹgbẹ oṣelu PPC, Olumuyiwa Fafowora ti ẹgbẹ oṣelu ADC ati Adebisi Ogunsanya YPP.