Atiku, Saraki, ẹgbẹ́ àwọn agbẹ́jọ́rò ta ko Buhari nípa Onnoghen

Awọn ọmọ Naijiria fesi lori ọrọ Onnoghen Image copyright @atiku, @bukolasaraki, @NigBarAssoc
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ Naijiria fesi lori ọrọ Onnoghen

Lọsan ọjọ ẹti ni aarẹ Buhari yọ adajọ agba, Walter Onnoghen nipo gẹgẹ bi adajọ agba orilẹede Naijiria to si fi ẹlomiiran rọpo rẹ.

Lọjọ kan naa ni aarẹ ti bura wọle fun adajọ Ibrahim Tanko Muhammed gẹgẹ bi adele ipo naa.

Lẹyin eyi ni ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti n tu ọ̀rọ̀ sita lori ẹrọ ayelujara.

Atiku Abubakar fesi loju opo Twitter rẹ pe aarẹ Buhari ṣe iṣe apaṣẹwaa ni pẹlu yiyọ to yọ adajọ Walter. Bẹẹ naa si ni awọn ọmọ Naijiria daa lohun.

Ni ti adari ile igbimọ aṣofin agba, Bukola Saraki, o ni, "iwe ofin yannana alakalẹ aatẹle lati yọ adajọ agba Naijiria o si ṣalaye ojuṣe ẹka ijọba mẹtẹẹta iyẹ ẹka idajọ, ẹka iṣofin ati ile iṣẹ aarẹ funrarẹ. O ni ki gbogbo awọn tọrọ kan nipa ijọba awa ara wa nile ati lẹyin odi dide lati lodi si igbesẹ ti ko ba ofin mu yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.

Bakan naa, ajọ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA naa ni igbesẹ aarẹ n ṣi ọna iparun fun idọgba niwaju ofin ati ilana to tọ lai tẹle.

Eyi jẹ jade ninu atẹjade ajọ naa ti aarẹ wọn, agbẹjọro agba Naijiria Paul Usoro fọwọ sí pé igbesẹ yii yatọ gbaa si ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'