BBC Gov Debates: Àwọn olùdíje l'Eko sọ èròngbà wọn f'árá ìlú

Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP)

ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀
Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀

Omobabinrin Ogunsanya pinu láti ṣe ohun merin gbòógì. Lara rẹ ni eto ẹkọ to peye, dida iṣẹ silẹ.

O pinu pe awọn Ọlọpaa ipinlẹ Eko yoo maa ṣiṣẹ di agogo mẹwa oru. Bakan naa, o dahun ibeere awn eniyan lori idọti ni ipinlẹ Eko. O mẹnu ba a pe awọn ijọba ibilẹ ni yoo maa moju to kiko idọti nipinlẹ Eko

Ọmọbabinrin Ogunsaya pari ọrọ rẹ pẹlu ibeere pe ki lo de tawọn ara Eko ṣi n jiya bayii? Ibeere yii si ni ijọba oun yoo wa ojutuu si bi o ba wọle gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko.

Ọgbẹni Babatunde Gbadamọsi (ADP)

Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀

Babatunde Gbadamọsi kọkọ sọ kulẹ kulẹ ibi ti o ti bẹrẹ awọn igbesẹ pataki kan ni igbe aye rẹ. Gbogbo ìwé tó ká je ti orile-ede Naijiria.

O bu ẹnu atẹ lu ilana iṣejọba to wa lori alefa bayii ni ipinlẹ Eko wi pe awọn ara ilu lo ni owo ti wọn n na kii ṣe ogun ẹnikẹni.

O bẹrẹ iṣẹ nilu oyinbo fun ọdun mẹtadinlogun ko to wa da iṣẹ tirẹ silẹ ni Naijiria. Ọdún mẹtàdínlógún ni wọn wá dà ilé ìṣe silẹ.

Gbadamọsi tẹnu mọ ọ pe iṣoro pọ nilu Eko. "Emi ni ẹni naa ta n sọ nipinlẹ Eko" ni ọgbẹni GBadamọsi sọ.

Ọmọlara Adesanya (PPC)

Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀

Ọmọlara Adesanya ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi obìnrin tó ní ìgboyà. O ti ṣiṣẹ ni ile ifowopamọ to ga ju lọ ni Naijiria. O fẹyin ti ni ọdun 2017 ni ipele oludari.

O tẹnu mọ ọ pe nítorí ìyá ń jẹ àwọn ènìyàn ìlú Èkó, oun fẹ mú àwọn tó wà lábẹ afara kúrò nínú ìyá. "Ilé ìwòsàn gaan ko ṣe fojú rí.

ìdí tí Ọmọlara fi ń díje ni pé orisirisi nkan lo dabi pé ó kú díè kaa tó nipinlẹ̀ Eko gẹgẹ bi o ṣe sọ ọ.

O pinu lati ṣe awọn nkan idunu fun ipinlẹ Eko.

Ọkan o jọkan ni awọn oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko ṣalaye ilana awọn ohun ti wọn ni lọkan lati ṣe fun ipinlẹ Eko.

Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP)

Image copyright Yetunde Olugbenga
Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀

Omobabinrin Ogunsanya pinu láti ṣe ohun merin gbòógì. Lara rẹ ni eto ẹkọ to peye, dida iṣẹ silẹ.

O pinu pe awọn Ọlọpaa ipinlẹ Eko yoo maa ṣiṣẹ di agogo mẹwa oru. Bakan naa, o dahun ibeere awn eniyan lori idọti ni ipinlẹ Eko. O mẹnu ba a pe awọn ijọba ibilẹ ni yoo maa moju to kiko idọti nipinlẹ Eko

Ọmọbabinrin Ogunsaya pari ọrọ rẹ pẹlu ibeere pe ki lo de tawọn ara Eko ṣi n jiya bayii? Ibeere yii si ni ijọba oun yoo wa ojutuu si bi o ba wọle gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko.

Muyiwa Fafowora (ADC)

Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀

Muyiwa Fafowora kọkọ ki ile iṣẹ BBC fun akitiyan lati fun awọn ti ẹsẹ kuku lanfani lati sọrọ faraye gbọ.

O ni nítorí pé ẹni tí ko bá jìyà rí kò lè mọ bí nkan ṣe rí. O pe ara rẹ ni olóṣèlú abẹle. "Ìjọba gbudọ mọ ìyà tó ń jẹ àwọn ará ìlú".

Fafowora ni ijọba oun ṣe tan láti ṣe metro line ni ìpínlè Eko, o ni ènìyàn 22m lo wà ní ìpínlè Eko bẹẹ si ni ohun irina bii metro line ti New York Experience ni won maa lo tí wọn ba ti dé bẹ.

Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀

Ipade ifọrọwerọ laarin àwọn oludije si ipo gomina ni ipinlẹ Eko waye lọjọ kẹrindinlọgọn oṣu kinni ọdun 2019.

Ni gbọngan ipade ìtagbangba ọhun pẹlu àwọn oludije sipo gomina ní ipinlẹ Eko gẹgẹ bi BBC Yoruba ṣe ṣe agbekalẹ rẹ, eto ti to ni ṣẹpẹ.

Àkọlé àwòrán Ipade itagbangba BBC Yoruba

Ipade yii yoo tun kún fún ohun to n jẹ ara ilu lọkan ju eyi ti a ti ṣe ni Ọṣun, Kwara, Nasarawa, Gombe, Imo, àti Akwa Ibom lọ.

Bí àwọn oludije ṣe ti n de wẹrẹ wẹrẹ ṣaaju akoko ti eto yoo bẹrẹ ni wọn n forukọ wọn silẹ.

Àkọlé àwòrán Ipade itagbangba BBC Yoruba

Awọn oludije ti yoo kopa bayii ni Babatunde Gbadamọṣi ti ẹgbẹ oṣelu ADP, Ọmọlara Adesanya fun ẹgbẹ oṣelu PPC, Olumuyiwa Fafowora ti ẹgbẹ oṣelu ADC ati Adebisi Ogunsanya YPP.

Bakan naa lẹgbẹ kan ni iforukọ silẹ awọn olukopa n lọ gẹgẹ bi awn naa ṣe ti n tete de sibi eto naa.

Àkọlé àwòrán Ipade itagbangba BBC Yoruba
Àkọlé àwòrán Ipade itagbangba BBC Yoruba

Awọn ẹṣọ ati oṣiṣẹ alaabo gan duro deede lati rii pe gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu abo nibi ipade naa.

Àkọlé àwòrán ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀