Níbo láyé kọjú sí: Ẹ̀rú èèyàn méjì ni ìyá mi gbé

Níbo láyé kọjú
Àkọlé àwòrán Níbo láyé kọjú

Àwọn alejo lori eto 'Níbo láyé kọjú' ti BBC Yoruba jẹ ko di mimọ pe dida ọmọ tọ gẹgẹ bi iya nikan kii ṣe arun.

Fisayọ Alabi duro lori ọrọ rẹ pe iya ti ori rẹ ba pe pere pere lee da ọmọ tọ ju iya ati baba ti aarin wọn kii gun ni gbogbo igba.

O ni igbeyawo ṣe pataki ṣugbọn bi ori awn mejeeji ko ba pe, igbeyawo naa ko le yanju.

Nitorinaa, pe obinrin ba ara rẹ ni ipo obi kan to n da ọm tọ, o gbudọ ṣara giri lati ṣe ẹtọ rẹ.

Ni ti arakunrin Ibrahim Owolabi, oun naa ko fi sihin sọhun. O ni bo ṣe kọju si eeyan kan, ẹyin lo kọ si ẹlomiiran.

"Awọn eeyan ko kii kọ igbeyawo wọn, ayẹyẹ igbeyawo ni wọn n ṣe". Owolabi ni kii ṣe pe awn eniyan naa kan nifẹ lati maa da tọ ọmọ ṣugbọn sababi ohun ti ko lee ran awọn ọmọ ọhun gaan lọwọ lo maa n fa a.

Àkọlé àwòrán Níbo láyé kọjú

Arabinrin Fisayọ sọ pe ninu iriri ohun, o ti ri ọpọlọpọ idile to jẹ wi pe oju aye ni wọn n ṣe, iya to lee gba ẹmi wn lo n jẹ wọn nile ọkọ.

Bakan naa ni Owolabi jẹ ko di mimọ pe iwa buruku obinrin mii lo sọ ọ di ẹni to n da ọmọ tọ.

Awọn mejeeji fẹnu ko wi pe kikọ ọmọ lẹkọ ṣe pataki yala baba wa nibẹ tabi ko si.