Ekiti 2018 Election:Irọ́ lásán ni ìgbẹ́jọ́ Fayemi tó jáwé olúborí

KAYODE-ELEKA Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òsèlú PDP lọ ilé ẹjọ́ láti tako ìdìbò tó gbé Kayode Fayemi wọlé gẹ́gẹ́ bí Gomina ìpínlẹ̀ Ekiti.

Gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti bu ẹnu atẹ lu idajọ ajọ to n gbọ ẹjọ eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ekiti.

Fayọse ninu atẹjade to fi lede, ti o si buwọlu sọ wi pe irọ lasan ni ijoko ajọ naa, nitori wi pe wọn ti mọ tẹlẹ wi pe Fayemi ni wọn ma a sọ wi pe o jawe olubori nibẹ.

O ni wi pe o ti to ọjọ mẹta si isinyii ti ẹgbẹ oselu APC ti n yọ, ti wọn si n dunnu silẹ wi pe awọn ni yoo jawe olubori, ati wi pe ohun iyalẹnu ni yoo jẹ fun oun, ka ni wi pe PDP lo jawe olubori.

Fayọse wa rọ awọn ara ipinlẹ Ekiti lati ma se sọ ireti nu, nitori wi pe otitọ yoo jọba nigba gbogbo.

Kayọde Fayemi jáwé oluúborí ní Tribunal

Ile ẹjo to n gbọ ẹjọ to suyọ lasiko idibo ti fa ọwọ Kayode Fayemi soke gẹgẹ bi gomina to wọle ni tootọ ni gomina ipinlẹ Ekiti lodun to kọja.

Ajọ Eto Idibo lorilẹede Naijiria lo kede Fayemi gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ekiti.

Ile ẹjọ naa gbe igbesẹ yii lẹyin ti wọn fagile ẹsun ti Olusola Eleka ati ẹgbẹ oselu PDP pe lati tako Fayemi to wọle ni Ekiti.

Ẹgbẹ oselu PDP lo gba ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ eto idibo lati tako idibo to gbe Kayode Fayemi wọle gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ekiti.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn olùgbọ́ BBC Yoruba fi èrò han lẹ́yìn #BBCGovDebate Eko

Amọ, ẹgbẹ oselu PDP ni anfaani lati lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn ko ba faramọ idajọ naa.