Nigeria 2019 Election: Ǹjẹ́ o mọ Alao Akala tó ń díje gomina ní Ọyọ?

Alao Akala Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Gomina tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Ọyo, Alao Akala ń díje dupò gomina lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú Action Democratic Party (ADP).

Ọjọ Kẹta, Osu Kẹfa, ọdun 1950 ni wọn bi gbajugbaja oloselu, Christopher Adebayo Alao-Akala to n dije dupo labẹ ẹgbẹ oselu Action Democratic Party (ADP) fun idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Ọjọ Keji, Osu Kẹta, ọdun 2019.

Alao-Akala lọ si ile iwe Government Technical College, Tamale, Ghana ati Ogbomoso High School, Ogbomoso.

Bakan naa ni oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu ADP naa lọ si ile iwe giga fasiti ti ilu Ibadan. Lẹyin naa lo bẹrẹ isẹ ọlọpaa titi to fi gba oye ADC si Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Nkan meje to yẹ ko o mọ nipa Alao-Akala ti Ọyọ

  • Alao-Akala ni gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ọyọ lati ọdun 2007 si ọdun 2011 labẹ ẹgbẹ oselu PDP.
  • Oloye Alao-Akala bẹrẹ oselu gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ New Dimension, lẹyin naa o darapọ mọ ẹgbẹ UNP, ko to di wi pe o jẹ Alaga Ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomoso ni ẹgbẹ oselu APP ni ọdun 1999 si 2002.
  • Alao-Akala lo da ẹgbẹ Ogbomoso Unity Forum to darapọ mọ ẹgbẹ oselu PDP.
  • Ọdun 2014 ni Alao-Akala kuro ni ẹgbẹ oselu PDP lọ si Labour Party nibi to ti dije dupo gomina ninu idibo gbogboogbo ti ọdun 2015.
  • Ọjọ Kẹrindinlogun, ọdun 2017 lo yapa kurọ ni ẹgbẹ oselu Labour Party lọ si ẹgbẹ oselu APC pẹlu ayẹyẹ nla.
  • Lẹyin idibo abẹlẹ ẹgbẹ oselu APC ti o ni kọnu-kọhọ ninu , Alao-Akala fi ẹgbẹ oselu APC silẹ lọ si ADP lati le dije dupo gomina ninu idibo ti yoo waye lọdun 2019.