#BBCGOVDEBATE: ADC fẹ́ tún ìpínlẹ̀ Ọyọ ṣe ní kíákíá -Olufemi Lanlehin

Lanlehin Image copyright WIKIPEDIA
Àkọlé àwòrán Olufemi Lanlehin ti lọ sojú fún Ìwọ Guusu ní ìpínlẹ̀ Ọyọ ní Ilé Ìgbìmọ̀ Asofin Agbà ní ọdún 2011 sí 2015.

Solagbade Olufemi Lanlehin to n dije dupo gomina ni ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe awọn ti ṣetan lati tun ipinlẹ Ọyọ ṣe ni kiakia.

Lanleyin to jẹ agbẹjọrọ ati oloṣelu ti fi igba kan ṣe sẹnetọ fun Iwọ Guusu ni ipinlẹ Ọyo ni Ile Igbimọ Asofin Agba ni ọdun 2011 si 2015.

Ile Iwe Ibadan Grammar School ni ilu Ibadan ati ile iwe girama Igbobi College ni ilu Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFalana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria

Nkan marun-un to yẹ ki ẹ mọ nipa Olufẹmi Lanlẹhin

  • Onimọ nipa eto ofin ni Lanlehin ni ile iwe giga fasiti ti Nigeria ni Nsukka ni ọdun 1977.
  • Ni ọdun 2011 ni Sẹneto Lanlehin soju Guusu Ọyọ labẹ ẹgbẹ oselu Action Congress of Nigeria.
  • Ni ọdun 2014, Lanlehin darapọ mọ ẹgbẹ oselu Accord Party lẹyin ti ẹgbẹ oselu ACN darapọ mọ ẹgbẹ oselu miran lati da ẹgbẹ oselu APC silẹ.
Image copyright Oyo ADC
Àkọlé àwòrán Ẹ wo Olufemi Lanlehin ti ADC tó ń dupò gómìnà ní Ọyọ!
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn olùgbọ́ BBC Yoruba fi èrò han lẹ́yìn #BBCGovDebate Eko

Lanlẹhin dibo mii ti ko wọle ninu rẹ.

  • Amọ ninu idibo gbogboogbo ọdun 2015 ni Lanlehin ti kuna fun Sẹnetọ Adesoji ti ẹgbẹ oselu APC fun ipo sẹnetọ Guusu Ọyọ.
  • Ni bayii, Lanlẹhin lo n dije fun ipo gomina ninu idibo gbogboogbo to nbọ ni Osu kẹta, ọdun 2019 yii labẹ ẹgbẹ oselu ADC ni ipinlẹ naa.
Image copyright Olufemi Lanleyin
Àkọlé àwòrán #BBCGOVDEBATE :ADC fẹ́ tún ìpínlẹ̀ Ọyọ se ní kíákíá-Olufemi Lanlehin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ