Emiliano Sala: Ìnira ní sísọnu Sala jẹ́ fún mi

Àkọlé àwòrán Ọsẹ tó nira julọ fún mi rèé- Neil Warnock

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Cardiff, Neil Warnock sọ pé bi Sala ṣe déedé pòórá jẹ́ àsìkò tó buru jùlọ fún òun nínú iṣẹ́ bọ́ọ̀lù.

Sala dawati lẹ́yin tó tọ́wọ́bọwe pẹ́lú mílíọ̀nu mẹ́ẹ̀dógún pọ́un ní ọjọ kọ́ọ̀kandínlogun, oṣu kinni, ọdun 2019.

O gbá àwọn tó ń sanwó fun lápò ara rẹ̀ láti tẹ̀síwájú nínú wíwá Sala ẹni ọmọ ọdún mẹ́jìdínlọ́gbọ̀n àti awakọ ofurufú David Ibbotson tí wọn jọ pọ̀ọ́rá lọ́jọ́ ajé lẹ́gbẹ̀ẹ́ Guernsey.

Cardiff padà sẹnu iṣẹ́ ní Arsenal fún Premier League lọjọ́ Iṣegun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFalana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria

'' Mo ti waà nínú iṣẹ́ alámojúto bọ́sọ̀lù bàyìí ó ti pé ogójì ọdún sùgbọ́n ìnira tí mo ri ni ọsẹ̀ yìí kò ní afiwe nínú ìrìnajò iṣẹ́ ti mo yàn láàyò" .

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionA ò ṣe àyọnusọ lóri ọ̀rọ̀ abẹ́lé Nàìjíríà-UK

Sala gboye Cardiff lẹ́yìn tó tọ́wọ́bọwe pẹ́lú Mílíọ̀nu mẹ́ẹ̀dógún pọ́un ní ọjọ kọ́ọ̀kandínlogun, osu kinni ń rìnrín ajo lati Nantes, lẹ́yìn tó ń ki àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó wà tẹ́lẹ̀ pé o dígbà ó ṣe ní oluulu Welsh.

Related Topics