Election Tribunal: À ó lọ ilé ẹjọ kòtẹmilọrùn - Ayodele Fayose

Image copyright Elekaofficial
Àkọlé àwòrán Election Tribunal: À ó lọ ilé ẹjọ kòtẹmilọrùn - Ayodele Fayose

Lẹ́yìn ìdájọ ilé ẹjọ́ tó ń ri si ẹsùn abájade ètò ìdìbò ti dá Kayode Fayemi ni oriṣiiriṣii ọrọ n jade.

Fayẹmi to dije lẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ko to jẹ Gomina Ipínlẹ̀ Ekiti ni wọn da láre gẹ́gẹ́ bíi ojúlówo ẹni to jáwé olúbori nínú ìdìbò tó waye lọ́dún tó kọja.

Gómìnà Ipínlẹ̀ Ekiti nígbà kan rí Ayodele Fayose tí Olúsọla Eleka lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) jẹ ìgbákeji fún ti fi atẹ̀jíṣẹ́ léde lóri twitter rẹ̀ lẹ́yìn èsì ìgbẹjọ́ náà.

O ní ìyàlẹ́nu ní kò bá jẹ́ fún òun tí kò ba lọ bí ó ṣe lọ nítorí kii ṣe àjòjì sí ẹnikẹni gẹ́gẹ bí ó ṣe jẹ́ ọwọ ijọba tó ń bẹ lóde.

O fí kún un pé ọ̀pọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló tí ń ṣe ajọyọ lóri abajade ìgbéjọ́ náà.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń fi èrò wọn hàn lórí ọ̀rọ̀ ti Fayose sọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFalana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionA ò ṣe àyọnusọ lóri ọ̀rọ̀ abẹ́lé Nàìjíríà-UK

"Mo rọ ẹyin ọmọ Naijíríà àti Ekiti kí ẹ si ní ìrètí pé gbogbo ìwà ìjẹ̀gàba lọ́wọ́ àwọn adájọ àti ilé ẹjọ kò ní pẹ dópin."

O ní jú gbogbo rẹ̀ lọ ou fẹ kí oludíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ ọjọgbọ̀n Olusola Eleka. " ó ti pọndandan kí ó ṣe aṣeyori."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYPP, ADC, PPC ni tòótọ́ ni pé ọmọ oninakuna nijọba Eko lasiko yii

" À ó gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àti ilé ẹjọ́ to ga jùlọ ti ó si ti pọndandan ki a jáwé olúbori"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn olùgbọ́ BBC Yoruba fi èrò han lẹ́yìn #BBCGovDebate Eko
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ