Day18: Àwọn oludije Naijiria ṣetán láti gba ẹ̀jẹ̀ nidibo 2019 - Falana #BBCElection2019
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Falana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria

Falana: kò dájú pé a tíì rí ààrẹ táa fẹ́ràn mẹ̀kúnnù ní Naijiria

O sọ̀rọ̀ lórí àwọn alágbara Naijiria lásìkò yìí pé àwọn to wa nipo kò ṣetan lati kuro bẹẹ awọn to kuro tẹlẹ naa tun fẹ gab ijọba pada lọnakọnaLink.

Agba ọjẹ agbẹjọro naa ṣalaye fun BBC Yoruba nikan ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe ominira Naijiria ti di omi ìnira mọ mẹkunnu Exclusive: Atiku dára ju Buhari ní ìlọ́po méjì - Obasanjo #BBCNigeria2019 lọwọ lasiko yii.

Fẹmi Falana ni ọrọ awọn alagbara ti wọn n ṣe ijọba Naijira lọwọlọwọ n fẹ apero ọmọ eriwo.

O ni awọn to n tukọ Naijiria kò ṣetan lati nu omije talaka nu, bẹẹ ko si aridaju fawọn to tun n gbiyanju lati debẹ pe wọn a nu omije mẹkunnu nu.

Fẹmi Falana ki oriki iru ijọba Tiwa-n-tiwa ti awọn eniyan Naijiria n fẹ ninu ifọrọwanilenuwo pẹlu BBC Yoruba.

O gbamọran fun awọn olugbe Naijiria pe o ṣeeṣe ki a mu iya kuro ni Naijiria ti gbogbo eeyan ba ṣetan lati jọ gbogun ti iwa ajẹbanu awọn olori wa.