#BBCGovDebate: Ìnákuna ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti pọ̀ jù - Gbadamọsi (ADP)
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

YPP, ADC, PPC ni tòótọ́ ni pé ọmọ oninakuna nijọba Eko lasiko yii

Fafowora: wọn tun buru ju ọmọ oninakuna lọ.

Babatunde Gbadamọsi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP ni pe inakuna ijọba ipinlẹ Eko ti pọ ju.

O sọrọ yii nibi eto Ipade Itagbangba ti BBC Yoruba ṣagbekalẹ rẹ fawọn oludibo lati raaye beere nipa nkan to n dun wọn lọwọ awọn oludije sipo gomina Eko.

Babatunde ni ọkan lara ọna tijọba oun le fi ri owo oṣu to yẹ san fawọn oṣiṣẹ ni nipa didẹkun owo inakuna ti wọn n na bayii pẹlu apẹẹrẹ inakuna ijọba.

Adebisi Ogunsanya, oludije ẹgbẹ YPP to wa nibi Ipade wa wi tẹnu rẹ yii naa ni oun faramọ ariwisi Gbadamọsi yii.

O ni ijọba ipinlẹ Eko ko tanmọlẹ to yẹ si bi wọn ṣe n na owó ipinlẹ naa.

O ni 'recurrent expenditure' (owo ti a ti n na tẹlẹ si iṣẹ kan) naa ni wọn n fojoojumọ ran mọ ẹnu.

Loju ti oludije fun ipo gomina yii, o ni : 'Account ijọba ipinlẹ Eko ko duro deede rara'.

Omolara Adesanya ti ẹgbẹ PPC ni gbogbo ara ni oun fimọ ariwisi naa pẹlu ẹri pé ijọba to na owo to tó 96.2 biliọnu naira si eto ilera ti kò kọ́ ile iwosan kan ṣoṣo jẹ ọmọ oninakuna.

O ni oun ko ri oogun, irinṣẹ iwosan tabi ẹrọ amunawa nile iwosan agbegbe rara ni eyi to jẹ ki ọlọpọlọ pipe ronu ibi ti ijọba n da owó naa si.

Fafoworo Olumuyiwa to n dije dupo gomina Eko lẹgbẹ ADC ni oun ko faramọ ariwisi Gbadamọsi.

O ni loju ti oun, ijọba ipinlẹ Eko buru ju ọmọ oninakuna lọ.

O ṣalaye pe owó ti ọmọ oninakuna ni lo n fi ṣofọ pẹlu ibeere pe kini ki a ti pe tawọn ti wọn n jẹ gbese de iran ọmọ wọn kẹta ti wọn de n fowo naa ṣofo

Nigba ti BBC Yoruba kàn sile iṣẹ ijọba ipinlẹ Eko lati ri aaye dahun si ariwisi yii, kọmiṣona fun ọrọ iroyin ati ifitonileti fun ipinle Eko fesi.

Ogbẹni Kẹhinde Bamigbetan bẹnu ẹtẹ lu ọrọ awọn oludije naa pé ko dara tó.

O ni irọ ni awọn odiwọn iye owó ti wọn nijọba n na danu ati pé ootọ inu nijọba fi n ṣe ohun gbogbo ti wọn n ṣe lasiko yi.