Day 18: Ṣé o fẹ́ mọ òtítọ́ nínu ọ̀rọ̀ ìpolongo àwọn oludije sípò aarẹ Naijiria? #BBCElection2019.

Eyi ni abala ikeji agbejade ileeṣẹ lori  bibeere ibeere lọwọ awọn oludije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.

Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ni awọn oludibo lorilẹede Naijiria yoo jade lati dibo lori awọn ohun tawọn oludije wọnyii ti sọ.

A gbe eto ayẹwo iroyin yii kalẹ lati ya iroyin bi eto idibo yoo ṣe lọ sọtọ kuro lara oṣelu ẹgbẹ kan  lati mọ awọn ohun to ṣe koko nipa eto iṣejọba
lorilẹede Naijiria.

Ṣugbọn bawo lawọn oludibo yoo ṣe mọ boya otitọ lawọn oludije n sọ?

Ẹ jẹ ki a yẹ ẹ wo.

Atiku Abubakar
57 miliọnu awọn ọmọ Naijiria ni ko lanfani si
omi to mọ gaara bẹẹni aadoje miliọnu ninu ọmọ orilẹede Naijiria lo n gbe ni
ayika to dọti laisi eto imọtoto gidi.
... (Iwe ilana ohun ṣiṣe fun aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP)
Ayẹwo
lati mọ otitọ.

Ootọ ni Atiku sọ. Ni ọdun 2015, ajọ ilera agbaye, WHO fi sita pe 57 miliọnu awọn ọmọ Naijiria ni ko lanfani si omi to mọ gaara bẹẹni aadoje miliọnu ninu ọmọ orilẹede Naijiria lo n gbe ni ayika to dọti laisi eto imọtoto gidi.

Eyi tumọ si pe ida mẹta ninu mẹrin ọmọ orilẹede Naijiria ni ko lanfani si ile igbọnsẹ to mọ

Aisan igbẹ gbuuru ti o ṣee dena nipasẹ omi to mọ gaara ati ile igbọnsẹ to mọ wa lara ohun to n gba ẹmi awọn ọmọde julọ lorilẹede Naijiria.

Ninu ọdun 2017, ajọ ilera agbaye woye pe o le ni ẹgbrun mẹrinlelaadọrin awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun marun lọ ti aisan igbẹ gbuuru ti ran lọ sọrun.

Ni ọdun 2018, ileeṣẹ eto ilera nijọba apapọ ṣeto iwadi kan lori ilera ẹbi

Wọn rii pe ilaji iṣẹlẹ aisan igbẹ gbuuru to n ṣe awọn ọmọde lorilẹede Naijiria n ṣẹlẹ ni ẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria, paapaa julọ ni ipinlẹ Sokoto ati Kebbi.

Nitori ọpọ awọn eeyan to wa ni awọn ilu nlanla, eyi to n mu ki eeyan kan ninu mẹta nibẹ o maa pin ile igbọnsẹ lo, eyi to si n mu ki ọwọja aisan o wọpọ.

Amọṣa, ọrọ yii  buru ju eyi lọ lawọn igberiko. Nigba ti orilẹede Naijiria gbe eto PEWASH rẹ kalẹ lọdun 2016, ida mẹtadinlọgọta ninu ọgọrun, 57% awọn olugbe igberiko lo lanfani si omi to mọ, ti ida mọkandinlọgbọn ninu ọgọrun si ni anfani si ohun elo igbsnsẹ eyi si kere si agbajọpọ apapọ orilẹede Naijiria ni ọdun to ṣaaju rẹ.

Ni oṣu kọkanla ọdun 2018, Aarẹ Muhammadu Buhari kede igbesẹ nnkan ko fararọ lẹka ipese omi ati imọtoto ti o si ṣefilọlẹ eto apapọ lori igbesẹ amojuto ilera ati imọtoto, WASH.

Ọkan lara awọn afojusun eto idagbasoke kariaye, SDGs ti ajọ iṣọkan agbaye UN gbe kalẹ ni mimu anfani omi to mọ gaara ati imọtoto waye fun tẹrutọmọ ni ọdun 2030 lati lee dẹkun awọn aisan bayii.

Muhammadu Buhari
Anfani omi ẹrọ to jẹ ida mejilelọgbọn ni ọdun 1990 ti lọ si ida meje ninu ọgọrun lọdun 2015; anfani imọtoto ti dinku lati ida mejidinlogoji lọdun 1990 si ida mọkandinlọgbọn lọdun 2015. Orilẹede wa ni ipo keji bayi laarin awọn orilẹede to n ṣe igbọnsẹ sita gbangba lagbaye nitori ida marundinlọgbọn ninu ọgọrun lo n ṣe igbọnsẹ si ita gbangba lorilẹede yii.
... Ọjọ kẹjọ oṣu kọkanla ọdun 2018 (Ọrọ apilẹkọ ti o ka ni gbọngan nla ile ijọba nilu Abuja)
Ayẹwo
lati mọ otitọ.

Ootọ diẹ wa lara ọrọ yii. Buhari sọ otitiọ nipa pe orilẹede Naijiria lawọn eeyan to n ṣe igbọnsẹ si ita gbangba pọ si julọ ṣekeji lagbaye, eyi to tums si pe wọn ko lanfani si ile igbọnsẹ to dara. Orilẹede India nikan eyi ti pọ ju ti Naijiria lọ.

O le ni miliọnu mẹrindinlaadọta ọmọ Naijiria to n ṣe igbọnsẹ si ita gbangba gẹgẹ bi ilana atọka idagbasoke ti banki agbaye gbe kalẹ ṣe sọ. Eyi n lọ si bii ida kan ninu mẹrin gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria.

Amọ iyatọ wa lori iye yii lẹlẹkunjẹkun. Ipinlẹ mẹta ti ọwọja igbọnsẹ itagbangba wa ni Kogi, Plateau ati Benue nibi ti  o le ni idaji awọn eeyan ibẹ ko ti lanfani si ile igbọnsẹ lilo, iyẹn gẹgẹbi iwadii ajọ ilera agbaye ati ajọ idagbasoke eto ẹkọ awọn ewe lagbaye, UNICEF gbe kalẹ lọdun 2016/2017.

O din ni ida marun awọn eeyan ipinlẹ bii Borno, Zamfara, Kano, Abia ati ipinlẹ Eko ti wọn n ṣe igbọnsẹ si itagbangba.

Loni ilọpo meji ọwọja ṣiṣe igbọnsẹ sitagbangba lawọn ilu nlanla lo n waye lawọn igberiko bayii, amọṣa ọwọja rẹ a maa pọ lawọn ilu ti eeyan pọ si, eleyi ton kọni lominu nipa awọn ipinlẹ bii Eko.

Oniruru aisan ninu eyi ti aisan gbẹmi-gbẹmi igbẹ gbuuru wa ti o si lee waye nitori awọn ounjẹ ati omi ti ko mọ ati ayika ti ko ni imọtoto, eto kolẹ-kodọti ti ko duro deede atawọn iwa ilera to mẹhẹ bii aikii fi ọṣẹ ati omi fọwọ.

Buhari woye adinku to niye ninu iye awọn to n lanfani si eto igbọnṣẹ to kunna to da lori oniruuru ile igbọnsẹ, omi to jagaara fun didana ati mimu.

Abajade iwadii ajọṣe kan laarin ajọ ilera agbaye, WHO ati ajọ idagbasoke eto ẹkọ awọn ewe lagbaye, UNICEF (JMP) gbe kalẹ lọdun 2015 fi idi eleyi mulẹ, ṣugbọn eyi yatọ si ohun ti Buhari n sọ.

Ni ọdun 1990, ajọ WHO woye pe ida mejidinlogoji ninu ọgọrun awọn eeyan lo lanfani si ohun elo imọtoto, eyi si ti di ida marundinlọgbọn lọdun 2015.

Wahala ọpọ ọdun pẹlu ti ni ipa pupọ lori awọn ohun elo amayedẹrun to lee faye gba ipese omi to ja gaara ati ile igbọnsẹ, paapaa julọ lawọn agbegbe ni ẹkun ila oorun ariwa.

Loni ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọpọ awọn ipinlẹ lo lanfani si omi to mọ gaara, ṣugbọn kii ṣe omi ẹrọ ijọba.

Ni gbogbo Naijiria, olu ilu Naijiria, Abuja nikan lawọn eeyan to n janfani omi ẹrọ ijọba ninu ile wọn ti pọ ju eeyan kan ninu mẹwa lọ.

Kọngadẹrọ ni ida kan ninu mẹta awọn ọmọ Naijiria ti n ri anfani omi to mọ fun mimu.

Ni apa ariwa, meji ninu marun ile to wa nibẹ ni ko ni anfani omi to mọ.

Kingsley Moghalu
Ijọba Naijiria ko ya owo sọtọ bo ti ṣe yẹ fun ẹka eto ilera ti a si ri wi pe ida marun pere 5% ninu ida ọgọrun ni wọn naa si ẹka yi laarin ọdun mẹwa to kọja. Fun idi eyi,orileede Naijiria kuna lati mu ileri Abuja ọdun 2001 to ṣe pẹlu awọn orileede miran lafrika pe ohun yoo na o kere ju ida mẹẹdogun 15% ninu ida ogorun owo isuna rẹ lori ọrọ ilera.
... (Iwe ilana ohun ṣiṣe fun aarẹ lẹgbẹ oṣelu YPP)
Ayẹwo
lati mọ otitọ.

Ootọ lọrọ yi.Laarin ọdun mẹewa sẹyin,ida mẹrin le diẹ 4.8% ninu ida ọgọrun owo isuna ọdọọdun ni ijọba apapọ n na sẹka ilera.

Ida owo ti ijọba apapọ na to poju lẹka ilera Naijiria jẹ ida mẹfa 6% lọdun 2012 sugbọn ninu owo isuna 2018 ati aba isuna 2019 owo ida mẹrin 4% pere ninu ida ọgọrun ni wọn ya sọtọ.

Eyi tunmọ si pe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wàá naira 1,900 ni ijọba n na lori ọmọ orileede Naijiria kọọkan lori ilera wọn

Naijiria wa lara awọn orileede 52 ti wọn pinu lọdun 2001 lati mu alekun ba owo ti wọn n na lori eto ilera si ida mẹẹdogun 15%.Orilede Tanzania nikan lo ti mu ipinu yi di mimuṣẹ.

Lati le kẹsẹjari lori ipinu yi,Naijiria gbọdọ na ilọpo mẹta iye to ya sọtọ fun eto ilera si 1.3 triliọnu naira lọdun 2019.

Eyi yoo mu ki iye ti ijọba n na lori eeyan kọọkan lekun si ẹgbẹrun meje naira 7,000.

Ni otitọ irufẹ alekun bayi ninu owo isuna yoo jẹ ki wọn le mu idagbasoke ba awọn nkan amulo to nilo atunṣe lẹka ilera.

Fun apẹẹrẹ,iyẹ ọmọ to ti gba abẹrẹ ajẹsara to le dena arun ko to idaji lorileede Naijiria.

Igbimọ amuṣẹya ijọba ti wọn gbekalẹ lọdun 2016 ṣe iṣiro pe ẹgbẹrun mẹtala naira pere ni iye ti wọn yoo na lati fun ọmọ kọọkan ni gbogbo abẹrẹ ajẹsara to yẹ ki o gba.

Àadọrun biliọnu Naira ni ijọba yoo na lori abẹrẹ ajẹsara fun awọn ọmọ ikoko lalai fi owo ti awọn oṣiṣẹ ilera ti yopo fun wọn labẹrẹ ati oogun naa yoo gba tabi owo ọkọ ti wọn yoo fi gbe wọn lọsi awọn ileeṣẹ ilera.

Lọpọ igba awọn eleyinju aanu lo ma n pese owo fun eto abẹrẹ ajẹsara.

Omoyele Sowore
Owo nina ọlọdani lori ilera to ida mẹ́rìnléláàdọ́rin ninu ida ọgọrun ti awọn eeyan n na ti eleyi a si ma ṣe akoba fun ọpọlọpọ mọlẹbi lorileede Naijiria.
... (Iwe ilana ohun ṣiṣe fun aarẹ lẹgbẹ oṣelu AAC)
Ayẹwo
lati mọ otitọ.

Ootọ lọrọyi.Ọpọ ọmọ Naijiria lo n na owo tarawọn lori ilera lawọn ile iwosan.Ninu isiro owo dọla kọọkan ti wọn ba na lori ilera,nnkan bi ida mẹta owo naa ni awọn alaisan fun ara wọn ma n na lati inu apo wọn ti ijọba si n na ida kan pere ninu rẹ.

Naijiria wa ni ipo keji lori akasọ awọn orileede ti iye owo ina lori itọju ilera ti ga ju lọ.Orileede Comosros lo saaju lafrika.Jakejado agbaye,Naijiria ni orileede to wa ni ipo kẹjọ.

Iye eeyan to forukọsilẹ lati jẹ anfaani ilera labẹ iléeṣẹ́ adójútòfò ìlera,NHIS, ṣi kere toun ti bi ko ṣe rọrun lati mọ iye eeyan ti o tiforukọ silẹ

Adele akọwe NHIS ti fojuda pe iye eeyan to forukọsilẹ kere si ida maarun ninu ida ọgọrun

Gẹgẹ bi iroyin ti ile ifowopamọ agbaye World Bank ko jọ lati ọdun 2009,awọn eeyan to le ni ida mẹta lo ti fi inira bọsi inu iṣẹ́ latari owo gọbọi ti wọn n san lati gba itọju.

Pẹlu bi o ti ṣe jẹ́ wi pe awọn to n wa itọju lo n san owo to pọju lati gba itọju,pupọ awọn mọlẹbi ti owo to n wọle fun wọn ko to dọla meji kii le gbọ bukata yi

Oun to bani ninujẹ ni pe Naijiria ko ni akojọpọ iroyin to munadoko lori ọrọ yi lati ọdun 2009.

Fela Durotoye
Gbogbo eeyan to ba ti kọja ọgọ́ta ọdun yoo laanfaani ilera ọfẹ.Awọn ti ko ba to ọmọọdun maarun yoo gba itọju ọfẹ.Awọn alaboyun naa yoo jẹ ninu anfaani yi.
... Ọjọ kọkandilogun ọdun 2019 (Ifọrọwerọ oludije Aarẹ)
Ayẹwo
lati mọ otitọ.

Yoo na ijọba ni nnkan bi $8,815,338,100.00 si $26,446,014,300.00 lọdun kan lati le pese ilera ọfẹ fun awọn to ti kọja ọgọta ọdun,awọn ti ko to ọdun maarun ati awọn alaboyun.

Lọdun 2015,ajọisọkan agbaye UN ṣe afojusun pe iye eeyan to kọja ọgọta ọdun ni Naijiria to 8,108,000

Owo ti wọn yoo na lati tọju ẹni to kọja ọgọta ọdun laarin ọdun kan sunmọ $2,852, gẹgẹ bi ohun ti ajọ to n ri si ifọwọsopọ eto ọrọ aje ati idagbasoke(OECD)

Owo ti wọn yoo na lati tọju gbogbo ẹni to kọja ọgọta ọdun laarin ọdun kan ni Naijiria yoo to $1,759,436,000.00

Lọdun 2015,wọn woye pe lati tọju awọn ti ko to ọmọ ọdun maarun ti iye wọn jẹ 31,109,000,ijọba yoo na $6,750,653,000.00 lọdun kan,fun awọn alaboyun ti iye wọn jẹ 7,445,100 iye owo $305,249,100.00 ni ijọba yoo na lọdun.

Lọwọlọwọ,iye ti ijọba n na lapapọ lori ilera jẹ $81, 640,000,00 amọ iye awọn ara ilu to n jẹ anfaani eto ilera ọfẹ ko to ida maarun ninu ida ọgọrun.

Ijiroro Tẹ ẹ ki a le jọ fikuluku

Ayẹwo
lati mọ otitọ.

A gbiyanju lati gbe awọn ohun to n lọ lagbo oṣelu kalẹ lai ṣegbe, lori awọn ohun to wa lojutaye jade.

Awọn ohun to ṣe pataki si awọn igberiko ni a gbaju mọ, gẹgẹ bii awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe ṣalaye rẹ.