Ìjọba Ààrẹ Buhari ti gbé Babachir Lawal,Oke áti ìyàwó lọ ilé ẹjọ́

Lawal ati Oke Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ìwà ìbajẹ́ àti síse owó ìlú básubàsu ni ìjọba fí kan Akọ̀wé Ìjọba Àpapọ̀, Babachir Lawal, Ayodele Oke àti iyawo rẹ̀.

Ijọba ti fun Akowe Agba lorilẹede Naijiria(SGF), Babachir Lawal, Adari Ajọ Eto Ọtẹlẹmuyẹ,NIA, Ayodele Oke ati iyawo rẹ, Folashade ni iwe ipẹjọ lori ẹsun iwa ibajẹ.

Ẹsun onigun mẹwa to da lori iwa ajẹbanu ati ni na owo ilu basubasu ni ijọba fi kan wọn.

Ile ẹjọ giga to wa ni ilu Abuja ni Lawal ati awọn marun un miran yoo jẹjọ ti Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC.

Bakan naa ni ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Eko yoo ma gbo ẹjọ ti wọn fi kan Arakunrin Oke ati iyawo rẹ, lẹyin ti wọn ba ọgọọrọ owo ni ile rẹ to wa ni Ikoyi, ni ilu Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHubert Ogunde ló m'órí mi yá láti di òṣèré

Ọjọ Kini, Osu Keji,ọdun yii ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ.