Akinwumi Ambode: Ilé aṣòfin Eko ṣèpàdé pàjáwìrì 'tórí Ambode

Gomina Ambode Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gomina Ambode

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti ni ayafi dandan ki gomina Akinwumi Ambode atawọn komiṣana rẹ ti wọn pe fara han niwaju wọn wa ṣe alaye bi wọn ṣe ṣe owo ilu.

Ile igbimọ tun jẹ ko di mimọ pe bi riru ofin yii ba tẹsiwaju, ile yoo lo ilana to wa ninu ofi eyi tii ṣe yiyọni nipo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIgba ọtun de fawọn afọju ninu eto idibo

Adari ẹgbẹ to pọ ju lọ nile, Ọgbẹni Sanai Agunbiade fi eyi lede nigba to m ba awọn oniroyin ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa sọrọ lẹyin ipade pajawiri ti wọn ṣe lalẹ ọjọru.

O ni ko sẹni to n ṣọ gomina lọwọ lẹsẹ gẹgẹ bi awuye wuye naa ṣe n lọ lawọn ibi kọọkan ṣugbọn koko ni pe riru ofin yii jẹ ohun ti ile aṣofin ko lee moju kuro lara rẹ.

Àkọlé àwòrán Gomina Ambode

Ọgbẹni Agunbiade ni ile aṣofin pinu lati ṣe ayipada iroyin ati iwoye ti kii ṣe ootọ́ to n ja kiri lori ipinu ile nipa Ambode lọjọ aje ọsẹ.

Nitori naa, latari ifẹhonu han awọn araalu tọrọ kan nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko lodi si yiyọ gomina Akinwumi Ambode lo mu ki awọn ọmọ ile igbimọ wọ inu ipade pajawiri lọ kanmọ kanmọ lẹyin ifẹhonu han naa.

Lori eyi, Ọgbẹni Agunbiade ni ile ko sọ pe ki gomina Ambode ma pari saa iṣejọba rẹ ṣugbọn tori awọn ọrọ to so mọ isuna ọdun 2019 ni ile fi pe e.

Ohun to sọ pe o jẹ koko ni wi pe Ambode ti bẹrẹ si ni na owo lati inu isuna ọdun 2019 eyi ti wọn ko tii gbe siwaju ile to si lodi si alakalẹ ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá ti ìpínlẹ̀ Ọyọ