Ààrẹ ní kí wọ́n wádìí oun tó ti bààlú Osinbajo fi já lulẹ̀

Ọkọ naa, Augusta AW139 Image copyright Laolu Akande/Twitter
Àkọlé àwòrán Ọjọ Abamẹta ni ọkọ naa, Augusta AW139

Ileeṣẹ Aarẹ ti paṣẹ pé kí wọ́n wádìí oun to fa ijàmba ọkọ ojufurufu ti o gbe Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo to ja lule ni Kabba, Ipinlẹ KogI nibi to ti lọ ṣe ipolongo ibo.

Ọjọ Abamẹta ni ọkọ naa, Augusta AW139 ja lulẹ ti ori si ko Osinbajo, minisita kan ati awọn mẹwaa miiran yọ.

Ileeṣẹ aarẹ ni wọn yoo ṣe iwadii lori ijamba naa gẹgẹ bii ilana iru iṣẹ bẹẹ.

Agbẹnusọ igbakeji, Laolu Akande, ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ si:

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni bii agogo mẹji aabọ ni ọkọ ofurufu naa balẹ ni papa iṣere kan ni Kabba ti fáànù ori rẹ si fo yọ.

Iwadii ko ti i fi han oun to fa ijamba naa gangan. Àwọn to wa ninu ọkọ naa ko fara pa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Gov Debates: Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn olùdíje yóò ṣe