Lassa Fever: Ọ̀nà márùn ún láti dènà ìbà ọ̀rẹ̀rẹ̀

Ekute n jẹ koriko
Àkọlé àwòrán,

Dokita mẹjọ lo ti ba arun lassa lọ ni Naijiria

Ẹgbẹ awọn ọmọ lẹyin Kristi, CAN ti kede pe ọgọrun un eniyan lo ti lugbadi aisan iba ọrẹrẹ ti gbogbo eniyan mọ si Lassa Fever ni ipinlẹ Ondo.

Alaga ẹgbẹ CAN ni ipinlẹ Ondo, Ẹniọwọ Ayo Ọladapo lo fi lede ninu lẹta ti wọn fi ransẹ si awọn adari ẹsin ni ipinlẹ naa lati se idanilẹkọọ fun awọn ara ile ijọsin wọn.

Agbegbe Ọsẹ ati Ọwọ ni ipinlẹ Ondo ni aisan naa ti n ja rainrain nilẹ.

Bakan naa, ni iroyin ni Adari Ile Iwosan Ijọba, FMC Ọwọ fi lede wi pe ko si aye fun awọn alaisan nitori ibi ti wọn ko awọn to ni aisan iba ọrẹrẹ si naa ti kun fọfọ.

Ọna marun un lati dèna Lassa Fever

Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan ti ko ni ẹrọ, amọ ti o ni itọju ti ẹni to ba ni aisan naa ba tete lọ si ile iwosan lati fi ara rẹ han.

Oríṣun àwòrán, Twipu.com

Àkọlé àwòrán,

Awọn gaari ti wọn n da silẹ lo n fa eku to ni aisan lassa lati tọ si ori garri yii, eleyi ti yoo fa aarun Lassa fun gbogbo ẹni to ba jẹ garri naa

  • Ọna ti a le gba dina aisan ti o wa lati ara ẹran igbẹ papa eku inu ile:
  • Ẹ sọra fun jijẹ eku tabi ẹran igbẹ.
  • Ẹ ma se sa garri sita gbangba.
  • Ẹ pa awọn eku to ba wa ni inu ile ati agbegbe yin.
  • Ẹ pa oko tabi koriko ti o ba wa ni agbeegbe, ki ayika naa le wa ni mimo ni gbogbo igba.
  • Awọn ohun elo ounjẹ gbọdọ wa ni inu ike ti ẹkutele ko lee de bẹ.
  • Ẹ sọra lati farakan ẹni ti o ma ni aisan iba ti kosi tete lọ.
  • Awon dokita tabi osisẹ ile iwosan gbọdọ sọra gidigidi, ki wọn si lo ibọwo tabi iboju ti wọn ba n toju ẹni to n se aisan.