Lassa Fever: Ènìyàn bíi 800 ni wọ́n funra sí pé ó ti ní ààrun náà ní Ondo

Èkúté
Àkọlé àwòrán Lassa Fever: Ènìyàn bi 800 ní wọn funra si pé o ti ní ààrun náà ní Ondo

Ó kéré tán ènìyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ló ti jẹ ọlọrun nípè lóri ààrùn Lásà jákèjádò Nàìjíríà látàri ǹkan bii oṣù kan tó ti bẹ sílẹ̀. Ilé ìwòsàn ǹla tó ń rí sí gbígbógun ti àjàkálẹ̀ ààrun ti fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn márùndínlọ́gọ́riń lé nígba ní o ti ní ààrùn náà nínú ẹẹdẹ́gbẹ̀rin ti wọn funra si pé o lé ti kó ààrùn náà.

Akòròyìn BBC Chris Ewokor jábọ̀ pé Ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlógun ní ọ̀rọ̀ náà ti kan nínú ààrun Lásà tó tun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ sílẹ̀.

Ìpínlẹ̀ Edo àti Ondo ní ìhà Gúúsù Nàìjíríà, ó sì dàbí ẹni pé àwọn ìpínlẹ̀ méjì yìí ni ọ̀rọ̀ náà kan jùlọ láárin ọṣẹ̀ méjì si àsìkò yìí bí ènìyàn ogoji ṣe ti lùgbàdì ààrùn ọ̀hún.

Òṣiṣẹ́ ètò ìlera mẹ́sàn ní ààrùn náà ti kọlu láwọn ìpínlẹ̀ mẹrin, tí ọ̀pọ̀ ẹmi si ti sùn láti ìgba ti ààrun Lásà ti bẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ to ń ri sí dídẹ́kùn àjàkálẹ̀ ààrun ṣe sọ.

Ààrun Lássà máà ń mú ènìyàn láti ara fifi ọwọ́ kan ounjẹ ti èkúté bá tọ̀ tàbí yàgbẹ́ sí. Ààrin ọjọ méjì sí ọjọ mọkanlélógun ni ó maa ń to jẹyọ.

Àpẹrẹ tó maa n jẹ́yọ ní ibà, kí ara má mókun, ori fífọ́, èbíbì àti ìgbẹ́, ikọ́, àti inú kíkan.