Ààrẹ Buhari: Irọ́ ni pé Leah Sharibu ti kú sí àhámọ́ Boko Haram

LEAH SHARIBU Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari: Irọ́ ni pé Leah Sharibu ti kú sí àhámọ́ Boko Haram

Lẹyin to ku ọsẹ kan ki idibo gbogboogbo ko waye ni orilẹede Naijiria, iya Leah Sharibu ti awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram jigbe lọdun to kọja ti ke gbajare si ijọba apapọ.

Iya Leah Sharibu, Abilẹkọ Rebecca Sharibu nibi to ti n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Abuja ni ki Aarẹ Buhari sa gbogbo ipa rẹ lati gba ọmọ oun lati ahamọ Boko Haram.

Ninu ọrọ rẹ, o ni nitori ọmọ oun kọ lati fi ẹsin Kristẹni silẹ ni wọn ko se fisilẹ lahamọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBoko Haram yóò dá Leah sílé

Leah to jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun pẹlu awọn ọmọ to le ni ọgọrun ti Boko Haram jigbe lati ile iwe Dapchi ni ipinlẹ Yobe lọdun to kọja.

‘Irọ́ ni pé Leah Sharibu ti kú sí àhámọ́ Boko Haram’

Bakan naa ni ijọba apa-pọ ti bu ẹnu atẹ lu iroyin to n ja rain nilẹ pe Leah Sharibu ti ku si ahamọ Boko Haram.

Minisita fun eto iroyin ati asa, Alhaji Lai Muhammed lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Ilorin, sọ wi pe iroyin ofege ni awọn eniyan n gbe kaakiri lori ẹrọ ayelujara lati le pe ijọba to wa lode loruko buburu saaju idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Satide, ọsẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ìdáhùn àwọn olùdíje Ogun ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́'

Lai Muhammed wa fikun wi pe awọn n sa gbogbo ipa awọn lati ri daju wi pe Leah Sharibu gba itusilẹ.