Nigeria Customs: Àwọn ìgbà tí ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ti pànìyàn lọ́nà àìtọ́

Ipaniyan ajọ ẹṣọ aṣọbode
Àkọlé àwòrán,

Ipaniyan ajọ ẹṣọ aṣọbode

Pẹlu iṣẹlẹ bi awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ aṣọbode ṣe yinbọn pa ara ilu kan laipẹ yii, oniruuru ibeere lo ti n jẹ jade.

Fun apẹrẹ ki ni ojuṣe awọn ẹṣọ aṣọbode?

Nibo gan ni aaye wọn wà, ṣe loju popo ni tàbí ní ibodè to jade kuro lorilẹede kan?

Ṣe o lẹtọ ki wọn maa gbe ibọn ati ki wọn maa deede yin lati fi dẹru ba alafia awọn eniyan?

Lori awọn ibeere yii ni awọn ọmọ Naijiria ti n wu oriṣiriṣi ọrọ jade ati isẹlẹ ti wọn ranti tabi ti wọn ni iriri rẹ pẹlu awọn ẹṣọ aṣọbode.

Lati ọdun bii melo kan sẹyin, lara awọn iṣẹlẹ ipaniyan to lọwọ awọn ẹṣọ aṣọbode ninu ti awọn eniyan n wu sita leyii.

  • Ni ọjọ kinni, oṣu karun ọdun 2016 ni agbegbe Oke-Odan ipinlẹ Ogun, eyi to jẹ iwọn bii kilomita mẹwaa lati Idiroko tii ṣe ilu ibode laarin orilẹede Naijiria ati Benin Reepublic, ṣaadede ni wọn ni awọn ẹṣọ aṣọbode naa ya wọ ilu bi aguntan ti ko loluṣọ ti wọn si bẹrẹ si ni da ibọn bo ẹnikẹni ti wọn ba pade. Iroyin naa ni ko din ni eniyan mẹẹdogun lapapọ to fara pa ati ti wọn ba iṣẹlẹ naa rin.
  • Bakan naa ni agbegbe yii kan naa, wọn yinbọn pa awọn ọmọ ẹkọṣẹ meji, Odude Amos Adeleke ati Azeez Yekini nigba ti wọn kọlu ilu wọn ti ọpọlọpọ si fara pa yana yana.
  • Ni ọj kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun 2019, igbimọ awọn oriade Yewa pe fun idajọ lori sun pe awọn ẹṣọ aṣọbode pa eniyan marun ni Owode-Yewa nigba ti wọn ya wọ awọn ile kan ati ṣọọ̀bu ti wọn ni ẹru ole lo wa nibẹ. Wọn ni ọṣe ti awọn oniṣẹ laabi yii n ṣe lagbegbe wọn ti n kọja afara da to si nilo iwadi gidi.
Àkọlé fídíò,

Àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà fohùn ránṣẹ́ sí ìjọ̀ba tí yóò wọlé

  • Ni ipinlẹ Ọyọ, ibanujẹ gbalẹ kan ni nkan bii oṣu mjọ sẹyin ti wọn fi ẹsun kan pe awọn ẹṣọ aṣọbode yii kan naa gba ẹmi agbẹ ẹni aadọrin ọdun kan, Lamidi Oke pe o da si ọ̀rọ̀ aawọ laarin wọn pẹlu awọn ọdọ ilu kan bi o tilẹ jẹ wi pe agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ aṣọbode ni ko si oṣiṣ awọn kankan to lọwọ ninu ẹsun naa.
  • Iru iṣẹlẹ yii kan naa tun waye ni agbegbe Owode-Yewa nipinlẹ Ogun nibi ti wọn ti ọta ibọn ẹṣọ aṣọbode ti ta pa akẹkọọ ile iwe giga fasiti Tai Solarin, Ijẹbu Ode nibi ikọlu laarin wọn ati awọn ọlọja irẹsi. Ẹbi ọmọ yii ke gbajare si ijọba apapọ lati ṣe idajọ to tọ.
  • Ni ipinlẹ Eko, awn ọlọpaa naijiria ni awọn ti mu oṣiṣẹ aṣọbode meje lori sun pipa arabinrin Patience Oni ti wọn si mu ki eniyan kan fara pa ni ile epo Forte Oil lba orita Badagry nipinlẹ Eko. iroyin sọ pe lakoko yii, ṣe ni awọn ẹṣọ aṣọbode yii n lepa yara ikorẹsi pamọ si aitọ kan to wa lẹba ile epo naa.
  • Eyi to wa loju ọpn to n ran kiri ni lọọlọ yii ni ti awọn ọ̀kan lara awọn arinrinajo kan ninu ọkọ Iyare laarin opopona Benin si Ọrẹ ti wọn ni oṣiṣẹ ajọ aṣọbode yinbọn pa latari pe wn ntahun sira lori ẹgbẹrun marun naira. Fidio iṣẹlẹ ṣi n tan ka ori ẹrọ ayelujara.