NDLEA jẹ gbajúgbajà olósèré, Baba Suwe ní 25,000,000

BABA SUWE Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ àwọn olósèré ló ti ń tọrọ àánú láti ọwọ́ àwọn ọmọ Naijiria láti lè fi tójú Baba Suwe tó ń se àìsàn.

Lẹyin ti iroyin jade wi pe Baba Suwe n se aisan, awọn akẹẹgbẹ rẹ ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati dide iranwọ si Baba Suwe.

Awọn olosere Nollywood naa gbadura fun iwosan rẹ lori ero ikansiraẹni Instagram wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Yorùbá: Temidayọ Ọlọfinsawo ní kò rọrùn láti darí òṣìṣẹ́ ọlọ́pọlọ pípé

Yomi Fabiyi gboriyin fun Baba Suwe fun ipa ribiribi to ko ninu igbesi aye rẹ ati bi o se da olokiki eniyan ninu isẹ osere.

Bakan naa ni wọn kesi Ile Isẹ to n gbogun ti lilo ogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA lati da miliọnu mẹẹdọgbọn rẹ ti o yẹ pada fun lẹyin ọdun mẹjọ ti wọn ti fẹsun kan Baba Suwe wi pe o gbe ogun oloro cocaine, amọ ti gbogbo iwadii fihan wi pe ko se bẹẹ.

Osu Kẹjọ, ọdun 1958 ni wọn bi Baba Suwe ni agbegbe Inabere ni ilu Eko ni ijọba ibilẹ Ikorodu, ko to di wi pe o bẹrẹ isẹ osere ni ọdun 1972 pẹlu fiimu rẹ, Ọmolasan ti Obalende se agbatẹru fun.

Related Topics