Ìdìbò Nàìjíríà: Ǹjẹ́ Ìṣẹ́ àti Òṣì buru síí ni?

Maapu ìlú Eko

Oríṣun àwòrán, DIGITAL GLOBE

Àkọlé àwòrán,

Ilú Eko níbí ti olówó àti tálákà ti ń gbé lẹ́gbẹ̀gbẹ́ ara wọn

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ó tóbi jùlọ nínú ètò ọ̀rọ̀ ajé nílẹ̀ Afíríkà àti olùpèsè epo rọ̀ọ̀bì lórilẹ̀ àgbàyé.

Sùgbọ́n, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí ní àwọn ènìyàn tó tó ìdajì tí wọn sì kún fún àwọn òtòsì paraku tí ìdá ọgọ́ta àwọn tó ń gbé àwọn ìlú ǹlá kò lágbára láti gba owó ilé tó kéré jùlọ níbẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn olówó tabua pọ ni Nàìjíríà, sùgbọ́n alafo nlá wà láàrin olówó àti táláká gidigidi jakejado gbogbo àwọn ilú nla.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Sajẹ: Mo n rọ awọn akẹẹgbẹ mi lati se suuru de asiko Ọlọrun

Sáájú ìdìbò gbogboogbo Nàìjíríà lọ́jọ́ kẹrìndínlogun oṣù kejì Eka BBC tó ń ṣetò ìwádìí (Reality Check) sàyẹ̀wò, bóya àwọn òtòsì ń tòsì síi tàbí alàfo olówó ń fẹ̀ síi

Aríyajiyàn tó jẹyọ

Ijọba tó ń bẹ lóde ní àwọn ń gbógun ti ìṣẹ́ àti òṣì sùgban wọn dèbi ru ìjọba tó kojá wipé àwọn ni wọn se owo epo àti ọ̀rọ̀ ajé mákumọku.

"kìí ṣe pé a ti rẹ́yìn òsì pátápátá, rárá ǹkan ti à ń sọ ni pé à ń gbógun ti ọ̀rọ̀ ìṣẹ́," Igbákeji Ààrẹ Ọ̀jọ̀gbọ̀n Yemi Osinbajo.

Ọ̀jọ̀gbọ̀n Osinbajo ní igbákeji ààrẹ tó bẹ lórí àléfà ààrẹ Muhammadu Buhari.

Olóri alátako fun Buhari ninu idibo to n bọ Atiku Abubakar sàlàyé pé ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ko tii buru jáì tó bi ó ṣe wà lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí.

"Ibéèrè tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìdìbò yìí ní pé: ǹ jẹ́ ó dárá fún ọ jú ti ọdun mẹ́rín sẹ́yìn lọ, ṣe o lówó síi ní àbí ò ń tòsì síí?"

Ètò ọ̀rọ̀ ajé wọ gàù

Láì pé yìí ni ètò ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà ṣe bí ẹni pe ó n gbé péélí lọ́dun 2017 lẹ̀yìn tí gbogbo ètò ọ̀rọ̀ ajé ti dẹnu kọle.

Ìdá ogun ni àwọn ti iṣe bọ lọ́wọ́ wọn tàbi tí wọn ò ri iṣẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bíí ààjọ tó ń ri si iye èèyan tilu ( Bureau of Statistics)

Nkan míràn ti ìwádìí ṣe awári ni pé èniyan tó to ìdá ọgọta nínú gbogbo èèyan ló ń gbe ninu òṣì paraku, ìgbelewọn yìí dá lóri ìyé àwọn ènìyàn to lé ra ounjẹ, wọ aṣọ́ tàbi ní òrule lori won.

Iwadii idile ti ijọba gbe yẹwo lọdun 2012

Ohunto dun ni ni lati rii pe ko si àwọn eroja iwadii to ṣẹsẹ waye, botilẹ jẹ pe àwọn iwadii lori bii àwọn eniyan se talaka to si n lọ lọwọ.

Ẹwẹ, àwọn ri ìwoe pé àwọn to dabi eni pe wọn talaka tẹ́lẹ̀ tii ń dinku báyìí.

" pẹlú bii àwọn eniyan ṣe ń pọ sii, ti iṣẹ si n di ọwọn gog, aridaju wa iyato ti yóò wà laàrin àwọn talaka àti olwo yóò ma fẹ si ni lajọ́ iwaju. Bongo Adi èni to jẹ onimo ètò ọ̀rọ̀ aje ní Lagos Business School.

Oríṣun àwòrán, Alamy Stock Photo

Àkọlé àwòrán,

Ajo UN sọ pe ọ̀pọ̀ àwọn eniyan to ń gbe ìlú ńla ló gbe adugbo ti kom bojumu

Osi ń tẹju mọ wa

Kò si aniani, iwoye awọn eniyan pe aparo kan ga ju ọkan lọ ń buru sii ni.

"O tí pẹ́ ti oye ti wa pe, inakuna owo ijoba, ikowojẹ àti aibọ̀wọ̀ fun ìlàna tó tọ fi kun ìdi ti àwọn òtòsì fi pọ, èyi ni ọ̀rọ̀ Abdulazeez Musa, Onwoye kan ni Nàìjiría.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ìpínlẹ Sokoto ló ni àwọn eniyan to tòsì jùlọ ní oríll-èdè yìí.

Òsì àti ìyà pọ gidi ní àwọn ìpínlẹ̀ Arewa ju àwọn ipinlẹ Guusu lọ

Ipinlẹ ló ni àwọn òtòsì to pọ jùlọ bí wọn se ni ìdá mkanlelọọgọrin nígba ti èniyan ìdá mọkanlélọ́gbọ̀n táláka ni Gúúsu pàápáà ni ìpínlẹ̀ Eko.

Omolara Adesanya, ọkan ninu àwọn oludije sipo Gomina ní ìpínlẹ̀ Eko sọ pe Iṣk ń ranju mọ wa ni.