Election Update 2019: Àwọn àwòràn àyàbá tójú wa rí lọ́jọ́ ìdìbò

Ẹ dá ẹ̀rín pẹ̀kẹ̀ẹ́ yín gẹ́gẹ́ bí a ṣe ní ká rán an yín létí àwọn àwòrán tó lè mú inú yín dún ká sáré ṣí ọkàn kúró lórí ohun tó le koko.

Awọn ara Ekiti n jẹ iyan
Àkọlé àwòrán,

"Aa ṣaa jẹun". Awọn ara Ekiti, ọmọ ọkọ ni wọn. Ko sohun to fẹ lagbara to lee di wọn lọwọ lilo iyan ati ọbẹ ẹfọ.

Oríṣun àwòrán, @KarickSKuyet

Àkọlé àwòrán,

"Lonii ni mo pade Sẹnetọ ẹni bi ọkan mi" lorin to gbẹnu arabinri yii loju opo Twitter rẹ lẹyin to sare ba Sẹnetọ Dino Melaye ya fọto tan, o ni ṣe lo da bii pe oun ṣẹṣẹ tọ ẹkun itọ tan bi inu oun ṣe dun.

Àkọlé àwòrán,

"Aa ṣaa jẹun". Aa ni febi para wa. Iyan lara Ekitii jẹ. Wọn ko fi para.

Àkọlé àwòrán,

"Awa o maye le". Ọrọ idibo ko si kan wa" lawọn ọdọ yii ṣe sọ oju popo di papa isere bọọlu.

Àkọlé àwòrán,

"Aa ṣaa wẹ, aa mumi, aa dana" lawọn ara Ilorin kan fi ko garawa ati basia sita lati lọ to pọn omi sile lọjọ idibo.

Àkọlé àwòrán,

"Aa ni kogba wọle tori idibo", lawọn ara ilu Kano yii fi n fa agbo wọn gbọ̀ọ́n gbọ̀ọ́n laarin ọja fun kata kara.

Oríṣun àwòrán, @delemomoduovations

Àkọlé àwòrán,

"Aye laa kọkọ jẹ, idibo yoo wa sopin". Oludari ati alakoso ile iṣẹiwe iroyin Dele Momodu Ovations pẹlu awọn ọrẹ rẹ n ṣara rindin ni ibudo idibo.

Àkọlé àwòrán,

"Emi naa yoo ṣaa jẹun". Awọn osisẹ alaabo pajawiri lo gba ọkunrin yii mu lasiko to n polowo igbo tantan tan ladugbo Berger nilu Eko

Àkọlé àwòrán,

"Ebi o kii wọnu ki ọrọ mii wọ ọ". Eyi lo jẹ ki ẹ ri aduru awọn koko irin yii lori adogan ni ilu Ilorin. Ounjẹ delẹ fun awọn tebi n pa.

Àkọlé àwòrán,

"Jẹ n ri i daju o!". Ṣe ẹ ranti akoko yii nibi ti Aarẹ Buhari ti na ọrun lati wo ta ni iyawo rẹ, Aisha dibo fun. Ṣe ni awọn mejeeji bu sẹrin nigba toju wọn ṣe mẹrin.

Oríṣun àwòrán, adesuwaiyare

Àkọlé àwòrán,

"Bo ṣe idibo bi o ṣedibo, lọkọ laya kan ṣaa lawa naa". Dọlapọ, tii se aya igbakeji aarẹ, ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo lo wa ọkọ rẹ si agọ idibo, ti awọn mejeeji ti dibo.

Àkọlé àwòrán,

"Mi o le wa ku". Iya agba yii to le lọgọta ọdun ati ọmọ rẹ gbe ẹni dani lọ si ibudo idibo lẹyin ti wọn ti rin kilomita meji.

Àkọlé àwòrán,

"Haa! aṣe o ti pẹ ti mo ti sun fọnfọn". Iru oorun wo la le ni arakunrin yii, Yusuf Sani sun ni Kano debi pe wọn pari ibo laaye idibo rẹ ki o to taji?

Àkọlé àwòrán,

"A kan n fi eleyii pa ironu rẹ ni o". A ṣi n fẹ kawọn adari wa ran ọdọ lọwọ.

Àkọlé àwòrán,

"Ọrẹ laa mọọ se" lọrọ awọn obinrin mẹta yii o ti wọn tun baa de ibi ti wọn ti lọ tẹka pẹlu ankoo ankara ti wọn jọ da.