2019 Election update: Wike ní àwọn ọmọogun fẹ́ 'dìtẹ̀ gbá'jọba' lọ́wọ́ òun

Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Nyesom wike

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ idibo aarẹ to kọja n da wahala silẹ laaarin gomina ipinlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ati ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria

Gomina Wike ti wi pe ileeṣẹ ọmọogun Naijiria n gbimọran ati 'ditẹ gbajọba'lọwọ oun.

Ni ọjọru ni Wike sọrọ yii lasiko to n fesi si ẹsun ti ileeṣẹ ọmọogun fi kan an pe o fẹ fi owo ra awọn oṣiṣẹ rẹ kan fun aṣemaṣe lasiko eto idibo apapọ ọjọ satide ko kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ rẹ yii waye lẹyin ti ileeṣẹ ọmọogun ti fi ẹsun kan gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike pe awọn oṣiẹ ile ijọba kan wa ti wọn gbe owo ẹyin tọ awọn ọmọogun kan wa lati ṣe awọn iwa aits kan ti yoo gbe gomina naa lẹsẹ lasiko idibo ọhun.

Wike ni oun ti pariwo sita lọpọ igba ṣaaju idibo apapọ to kọja lọ pe ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ti sọ ara wọn di ohun elo awọn eeyan kan lati ṣe magomago lasiko idibo naa ati lati da rukerudo silẹ ni ipinlẹ ọhun.

O ni oun si tun sọọ sita nigba naa pe wọn n lepa ẹmi oun eleyii ti ko si ẹnikẹni lara awọn ọga ileeṣẹ ọmọogun Naijiria to fesi tabi gbe igbesẹ le lori.