Election Update 2019: APC kò ṣe mọ̀dàrú, PDP ló fẹ́ gbà'jọba tipátipá

Election Update 2019: APC kò ṣe mọ̀dàrú, PDP ló fẹ́ gbà'jọba tipátipá

Ẹgbẹ́ oṣelu APC nipinlẹ Eko ti mu alaye wa lori iṣẹlẹ jagidijagan to waye lasiko idibo Aarẹ lawọn agbegbe kan nipinlẹ naa.

Eyi n waye lẹ́yin ti ọpọlọpọ fidio àti iroyin fi han bi awọn kan ti da oju ibo bolẹ ni awọn agbegbe bii Surulere ati Ago Palace Way, Isolo nilu Eko,.

Akọwe ẹgbẹ oṣelu APC nilu Eko, Wale Ahmed ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ BBC ti ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lo da ibo naa ru.

Ogbẹni Wale Ahmed ni APC ko ni idi kankan lati da wahala silẹ tabi lati da ibo ru nitori wipe ẹgbẹ PDP lo fẹ gba ijọba ni tipatipa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: