#BBCNigeriaDecides: Ohun ti mo gbé dání fún Kwara ju ti APC àti PDP lọ -Yinka Ajia
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yinka Ajia: ìbẹ̀rù Ọlọrun ni mo fẹ́ fi tukọ̀ Kwara ti mo ba wọlé

Ohun to n ṣelẹ ni Kwara lo n ba mi ninujẹ ni mo fi jade dupo gomina lasiko yii.

Omowe Abdulmumeen Yinka Ajia lo n dije dupo gomina nipinlẹ Kwara labẹ ẹgbẹ oṣelu Abundant Nigeria Renewal Party.

O ṣalaye fun BBC Yoruba lórí èròńgbà rẹ̀ fún ìpínlẹ̀ Kwara pé ohun to lagbara loun ni lọkan lati ṣe fawọn eniyan Kwara ti oun ba wọle.

Yinka Ajia ni oun ko ni owo pupọ tabi baba isalẹ kankan ṣugbọn ọkan oun balẹ pé ti wọn ba dibo fun oun erongba oun a san awọn eniyan Kwara si daadaa.