Àwọn adarí ìjọ olókìkí tó ti f'ara ko imí ẹ̀sùn àgbèrè ní Naijiria

Iginla, Suleiman, Fatoyinbo ati Kwakpovwe

Ẹsun agbere ko jẹ ajoji si awọn ile ijọsin kakakiri agbaye. Ṣugbọn ni orilẹede Naijiria, awọn adari ijọ olokiki bii meloo kan ti fi ara ko imi ẹsun agbere, eyi ti iroyin rẹ yani lẹnu pupọ.

O da bi ẹni pe ọdọọdun ni iroyin iru ẹsun agbere naa maa n jade nipa awọn pasitọ olokiki ni orilẹede Naijiria.

Ni ọpọlọpọ igba, awọn pasitọ ti ọrọ kan maa n funra wọn jẹwọ wipe awọn ti ṣe aṣemaṣe ni tootọ, ti wọn a si tọrọ idariji ẹsẹ. Ni igba miiran, wọn a ni irọ ni wọn pa mọ awọn.

Awọn olori ijọ ti ọrọ yii ti ta ba ree:

1. Joshua Iginla

Image copyright Champions Royal Assembly

Adari ijọ Champions Royal Assembly to wa ni Kubwa, Abuja yii tẹ pẹpẹ ọrọ ninu isin ọjọ Aiku nigba to jẹwọ niwaju ijọ rẹ wipe oun jẹbi ẹsun agbere kan ti iyawo oun fi kan oun ati wipe nitori naa, oun ati iyawo oun ti ṣetan lati kọ ara silẹ.

Ninu fidio ti a ri wo lori ayelujara, Iginla ni oun ati iyawo oun ti n ja lori ọrọ naa fun bi ọdun meje. O ni oun pinnu lati wa jẹwọ niwaju ijọ nitori wipe oun fẹ alaafia fun ọkan oun.

2. Johnson Suleiman

Image copyright OFM/ Stephanie Otobo

Alufaa yii, to jẹ olori ijọ Omega Fire Ministries International ti oriko rẹ wa ni Auchi nipinlẹ Edo, wọnu iroyin ni ọdun 2017 nigba ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Stephanie Otobo fi ẹsun kan wipe o fun oun loyun, o si ja oun silẹ. O fi awọn ẹri kan to jọ awọn atẹjiṣẹ ori ẹrọ ilewọ han ninu eyi ti oun ati pasitọ naa fi ọrọ ifẹ ṣọwọ sira.

Ko pẹ lẹyin rẹ ni a tun ri arabinrin naa to farahan niwaju ijọ lati ni oun pa irọ mọ adari ijọ naa ni. O ni awọn kan lo ran oun niṣẹ ibi naa.

3. Biodun Fatoyinbo

Alufaa to gbafẹ yii ni adari ijọ COZA to fi Abuja ṣe ibudo. Ọrọ ẹsun agbere rẹ fa awuyewuye lọpọlọpọ ni ọdun 2013 nigba ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ese Walter jade lati jẹwọ agbere to ni awọn jọ ṣe. Ẹsun arabinrin naa tilẹ lagbara de bi pe, o ṣalaye bi alufaa naa ti maa n ba a lo pọ kakakiri gbogbo orilẹede ti wọn jijọ maa n rin irin ajo si. Ara awọn alabaṣiṣẹ pasitọ naa ni Walter ni asiko naa.

Lẹyin ẹsun naa, Fatoyinbo ni oun yoo fesi si ẹsun naa nigba ti asiko ba to. Ṣugbọn titi di oni, alufaa naa ko fesi si ẹsun naa.

4. Chris Kwakpovwe

Image copyright Manna Prayer Mountain Ministry

Biṣọọbu ijọ Manna Prayer Mountain Ministry yii lo n kọ iwe Our Daily Manna. Ni ọdun 2017, iroyin ṣi kuro ni ori bi iṣẹ iranṣẹ rẹ ṣe lagbara to si igbohunsilẹ ti wọn ni o fi han nibi ti o ti n sọ ọrọ ifẹ fun arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Rita Ibeni.

Kwakpovwe ni irọ ni wọn pa mọ oun nigba naa, ṣugbọn ọpọ iroyin lo jade lori ọrọ naa.

Ṣugbọn ki ti ẹ ni ti awọn alufaa olokiki ti ọrọ agbere n jẹyọ lori wọn?

BBC Yoruba ba gbajugbaja onwoye kan toun naa jẹ ojiṣẹ Ọlọrun, Femi Aribisala lori ọrọ yii.

Otitọ kan ko si ninu ijọ mọ - Aribisala

Aribisala sọ fun BBC Yoruba wi pe, ko si ootọ kankan ninu pe adanwo maa n tẹle awọn olori ijọ ju awọn ẹlomiiran lọ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni eniyan ẹlẹran ara lasan niwọn ati wi pe, ọpọlọpọ olori ijọ kii ṣe eniyan Ọlọrun bi aye ṣe maa n sọ. O ni eniyan buruku ti o kan n lo orukọ Ọlọrun ni ọpọlọpọ wọn.

Aribisala tẹnu mọ ọ pe awọn olori ijọ miiran kan n lo ipo wọn lati ṣe agbere lasan ni.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

'Kọ́kọ́ kànsí àlúfà lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó'

'Ọdún 2019 pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kó lọ́wọ́ dé'