LASBCA sọ̀rọ̀ lórí ilé wíwó

LASBCA sọ̀rọ̀ lórí ilé wíwó

Adari ajọ to n ri si ọrọ ile kikọ nipinlẹ Eko, LASBCA Ọgbẹni Lekan Ṣhodẹinde ọpọ ile ko ba ti di wiwo ti awọn onile ba tẹle ilana ajọ LASBCA nipinlẹ Eko.

Shodẹinde to ba BBC Yoruba sọrọ lori ile to ya lulẹ lagbegbe Oke Aarin, Lagos Island, sọ pe o ṣeni laanu pe ọpọ onile lo maa kọ eti ikun si ijọba lori ofin ti ijọba la kalẹ lori ile kikọ nipinlẹ Eko.

O ni ile iṣẹ LASBCA kii ṣe ile iṣẹ wole wole, o ni aitẹle ofin ijọba lori ile kikọ lo jẹ ki ajọ LASBCA maa wo awọn ile ti ko dangajia.