Adam Johnson: Agbábọ́ọ́lù Sunderland nígbà kan rí jáde lẹ́wọ̀n lẹ́yin ọdún mẹ́ta

Adam Johnson Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Adam Johnson lọ ẹ̀wọn ọdun mẹ́fa ni 2016

Baba agbabọọlu Sunderland ati Ilẹ Gẹẹsi nigba kan ri, Adam Johnson ni inu oun dun pe ọmọ oun ti jade lẹwọn

Johnson gba bọọlu fun Middlesbrough, Manchester City ati Sunderland ki wọn to ju u si ẹwọn ọdun mẹfa ni 2016 nitori wipe o ba ọmọ ọdun mẹẹdogun kan ṣere ifẹ.

Baba rẹ, Dave ba awọn akọroyin sọrọ ni iwaju ile ọmọ rẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni Castle Eden, County Durham.

Image copyright Danny Lawson/PA Wire
Àkọlé àwòrán Ẹwọn HMP Moorland to wa lẹgbẹ Doncaster ni Johnson ti lo ọdun mẹta

Johnson, to gba bọọlu fun ikọ England nigba mejila ni wọn da silẹ ni ẹwọn lẹyin to ti lo ilaji ẹwọn rẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni wipe o fẹ ba ọmọdebinrin naa ṣe ere ifẹ, to si fi ẹnu ko o ni ẹnu. Bi ẹjọ naa ṣe bẹrẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Sunderland yọ ọwọ ninu iwe adehun bọọlu rẹ, eyi ti wọn ti n fun ni ẹgbẹrun lọna ọgọta pọun ni ọsẹ.

Image copyright Durham Police
Àkọlé àwòrán Inu ọkọ Range Rover yii ni wọn ni o ti fẹ ba ọmọdebinrin naa ṣe ere ifẹ

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDemilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé