Ìdìbò Kano kò fararọ, bẹ́ẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ to kù náà kò ní ìfọ̀kanbalẹ̀

Àkọlé àwòrán Ìdìbò Kano kò fararọ, bẹ́ẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ to kù náà kò sí ní ìfọ̀kanbalẹ̀

Oludije dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbk òṣèlú People's Democratic Party (PDP) sọ pe pẹ̀lú ọlọkan-òjọkan ìròyìn jákejádò Nàìjíríà tó tẹ òun lọ́wọ́ lórí àtúndi ìdìbò tó wáye lónìí, kò si ibi ti ìdìbò náà ti lọ ni irọwọ́rọsẹ̀.

Atiku fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀lóri ẹrọ̀ ay;elujara twitter rẹ̀ pé níwọ̀n ìgbà ti kìí ṣe gbogbo ìpínlẹ̀ ló ń ṣe ètò ìdìbò lónìí, ó yẹ ki gbogbo ǹkan lọ ni ìrọwọ́rọsẹ.

Ní ipínll Kano, oniruuru ìṣẹ̀lẹ̀ ló wáye ti àwọn miran till pàdánu ẹmi wọn, ti ìdá ọgọrin nínu ìdá ọgọrun ibùdó ìdìbò sì ni kónukọhọ nínú.

Àkọlé àwòrán Ìdìbò Kano kò fararọ, bẹ́ẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ to kù náà kò sí ní ìfọ̀kanbalẹ̀

Ajọ eleto ìdìbò ṣì ń réti la'ti ka èsì ìbò nibi tí ìdìbò ba ti waye.

Ọ̀pọ̀ àwọn budo idibo ti BBC ṣe abẹwo si fi han pé àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò kò till yoju tí àwọn janduku àti ẹru ikú àwọn olṣelu si ń le àwọn olùdíbo àti àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣelú dànù

Ojọgbọ́n Sheu Risqua tó jẹ ọga INEC ní ìpínlẹ̀ Kano sàlàyé pé gbogbo ǹkan to ṣẹ̀lẹ̀ páta ni àwọn mọ pàápàá jùlọ bi àwọn janduku ṣe da gbogbo nkan ru, sùgbọ́n àwọn ati ajọ eléto ààbo ń fikulukun láti yanju gbogbo rẹ

Ní Benue, ọga àjọ INEC Nentawe Yilwatda sàlàye fun BBC pé lẹ́yìn ti wọn pín gbogbo òhun elò ìdìbò tán ni ibudo idibo Ijoba ibilẹ Ukum ní àwọn janduku dé ti wọn bẹ̀rẹ̀ si ni dàbọn bolẹ.

Wọn gba gbogbo ohun elo idibo wọn si sun nina, sùgbọ́n kò si ọmọ eleto idibo kankna to farapa, ó ní òun ti pàṣé fun àwọn ọmọ olgun láti ko gbogbo òṣìṣẹ́ àjọ INEC kúrò ní agbégbé náà.

Awọn ipinlẹ̀ mẹ́tàdinlógun lóyẹ ki ètò ìdìbò ti òni ti wáye, Kano, Benue, Sokoto, Bauchi, Lagos, Rivers

Àkọlé àwòrán Bayi ni idibose lo lapa ibikan ni Kano
Àkọlé àwòrán Alaboyun ni ànfani lati lọ sibi atundi ibo ni Plateau
Àkọlé àwòrán Idibo ni Drass ati Bogoro Ipinlẹ Bauch