PDP: APC ń kéde pé Saraki ni ipa tó ń ko láti yan olori ile asofin agba

Bukola Saraki Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ ilé ìgbìms aṣofin ko lọ́wọ́ nini bi àó ṣe yan ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ túntún

Ẹgbẹ́ òṣèlú People's Demoractic party (PDP) àti awọn sẹnatọ rẹ̀ ti bu ẹnu àtẹ lu ààrẹ Muhammadu Buhari, ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti alága ẹgbẹ́ náà, Adams Oshiomole lóri ibi ti wọn fi si nípa ẹni ti yoo adari ilé igbimọ aṣofin apapọ to ń bọ.

Àwọn sẹnatọ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, nínú àtẹjade kan tí olori ọmọ ilé tó kéré jùlọ, Abiodun Olujimi àti Sẹnatọ Dino Melaye fọwọ́si sọ pé, ki wọn yọ ṣenatọ Bukola Saraki kúrò nínú awuyewuye àti eto ti wọn fẹ́ lò, láti yan ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin kẹsán.

PDP ní gbogbo àwọn sẹnatọ àti ọmọ ile ìgbìmọ̀ aṣojú ṣofin ti wọn dibò yan ló lẹ́tọ̀ọ́, láti dari ile ìgbìmọ̀ aṣofin.

Atẹjade àwọn asofin agba PDP yìí wáye nitori àwọn ìròyìn kán tó ń nàka sí ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àgbà, sẹnatọ Bukola Saraki pé o ń pinnu láti lọ́wọ́ si ọ̀nà ti ààrẹ tuntun ilé aṣofin ẹlẹkẹsan yóò fi dide.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù

Lọjọ Ajé ni Oshimole ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asoju-sofin ti wọn dibo yàn pẹ́lú àṣẹ pé, dàndàn ni kí ẹgbẹ́ APC ṣe agbédide ẹni ti yóò dari láàrin ẹgbẹ́.

Àwọn sẹnatọ nínú atẹjade ti wọn fi sita kìlọ̀ pé, àwọn aṣofin ẹgbẹ́ oṣèlú PDP kò ní gba ki ará ìta lọ́wọ́ nínú bi àwọn yóò se yan adari tuntun.

Image copyright NASSofficial
Àkọlé àwòrán Ki ẹgbẹ oselu APC lọ ki owo ọmọ wọn bọsọ oo, ko si éni to le fa ààrẹ kalẹ

Awọn sẹnatọ ọ̀hún fẹ̀sùn kan pé, APC ń fún ara ilú ni òyé bi ẹni pé Saraki ni ipa tó ń ko láti yan olori ile igbimọ asofin agba fun sáà tó ń bọ.