Tinubu Colloquium: Ìṣẹ́gun APC ní ìdìbò 2019 ni ẹ̀bùn pàtàkì tí mo rí gbà fún ọjọ́ ìbí mi

Ibudo apero Tinubu colloquium 2019 Image copyright Ileowo Kikiowo
Àkọlé àwòrán Ọdọọdun ni apero yii maa n waye fun ijiroro lori awọn koko ohun to n lọ lawujọ

Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu ti sọ pe iṣẹgun ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ni idibo aarẹ to waye lorilẹede Naijiria ati ibo ile aṣofin apapọ ti ẹgbẹ naa ti moke jẹ ẹbun pataki ti oun ri gba fun ayẹyẹ ọjọ ibi oun fun ọdun 2019.

Aṣiwaju Tinubu sọrọ yii lasiko to fi n ki awọn eeyan ku abaṣe nibi apero ti wọn gbe kalẹ fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, Bola Tinubu Colloquium to waye ni ọjọbọ nilu Abuja.

O ni lẹyin ti ipolongo idibo ati idibo gangan ti pari bayii, igbesẹ fun itẹsiwaju ọrọ aje orilẹede Naijiria lo yẹ ki ijọba aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Yẹmi Ọṣinbajọ o gbe yẹwo bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọmọkùnrin tó pa ọmọ igbákejì Gómìnà Ondo gba ìdàjọ́ ikú

'Fashọla, o ò dẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run!'

'Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ló gbégbà orókè nínú ìwà jẹgudujẹra ní Nàìjíríà'

O ni ọrọ akọmọna ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC, Next level ko gbọdọ pari sibẹ o nitori naa gbogbo igbesẹ eto idagbasoke ọrọ aje to wa ninu akọmọna naa bii fifẹ oju eto ọrọ aje, mimu idagbasoke awọn obinrin ati ọdọ lọkunkundun sii lo yẹ ko jẹ ijọba logun bayii ki orilẹede Naijiria naa le janfani ayipada rere gbogbo to ba n waye lawujọ agbaye.

Bakan naa lo tun rọ ijọba aarẹ buhari lati tun ero rẹ pa lori iroyin kan to n jade kiri pe o n gbimọran ati fi kun owo ori awọn ọja rira lorilẹede Naijiria, VAT.

Tinubu ni ohun to yẹ ki ijọba o mojuto bayii ni imugbooro iye awọn to n san owo ori.

Image copyright CBN Gov Akinsola
Àkọlé àwòrán Tinubu ni Next level kìi ṣe ọrọ akọmọna ipolongo idibo lasan, ilana ìdagbasoke ti ijọba APC gbọdọ mulo ni

Ninu ọrọ to fi ran igbakeji rẹ si ibi apero naa, Aarẹ Muhammadu Buhari ni oun ko ni kọ ipakọ si ileri oun lati gbe awọn ọmọ orilẹede Naijiria de ipo ati aaye ti o yẹ wọn.

O ni ohun ti yoo gba aaye to lapẹrẹ ninu eto iṣejọba oun bayii ni ipese ohun amayedẹrun fun araalu.

Lara awọn to wa nibi eto naa ni igbakeji aarẹ, Yẹmi Oṣinbajo ati aya rẹ, awọn gomina ipinlẹ atawọn ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan to fi mọ awọn ọbalaye gbogbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Ọkan o jọkan awọn alamojuto ati olotu ẹka iṣakoso gbogbo lorilẹede Naijiria ni wọn farahan nibi apero naa.

Akori apero ọhun ni "Next Level Work for people"

Ninu ọrọ tirẹ, Okechukwu Enelamah to jẹ minisita fun idaleeṣẹ silẹ, karakata ati idokoowo ni ijsba ti gbe eto kalẹ fun tita awọn ohun elo ti wọn ba ṣe lorilẹede Naijiria si oke okun eyi to pe ni MINE. O ni igbesẹ yii yoo mu ki ẹka ileeṣẹ o gbooro si ni ida ogun ninu ọgọrun. O ni eyi yoo tun pese iṣẹ fun awọn eeyan ti o to miliọnu kan abọ ni iye.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí