Nnamdi Kanu: Ilé ẹjọ́ wọ́gilé béèlì Nnamdi Kanu

Nnamdi Kanu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba onídúró rẹ̀ tí Nnamdi Kanu sá kúrò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Ile ẹjọ ti paṣẹ ki awọn agbofinro o pada lọ fi panpẹ ọba mu olori ẹgbẹ ajijagbara ẹya Biafra, Nnamdi Kanu.

Ile ẹjọ giga apapọ kan ni ilu Abuja fagile oniduro rẹ ni ọjọbọ leyin eyi to ni ki wọn lọ gbe pada si ahamọ ọlọpaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adajọ to gbọ ẹjọ naa, Onidajọ Binta Nyako ni eredi aṣẹ yii ko ṣẹyin bi Nnamdi Kanu ti ṣe ti kuna lati fara han niwaju ile ẹjọ naa lati igba ti wọn ti gba oniduro rẹ ni oṣu kẹrin ọdun 2017.

Ile ẹjọ naa paṣẹ pe igbẹjọ naa gbọdọ tẹ siwaju, pẹlu aṣẹ pe ki awọn agbẹjọro to wa nivdi ẹjọ naa o mu ọjọ igbẹjọ tuntun ki igbẹjs lee tẹsiwaju, lai naani boya kanu yọju tabi ko ysju.

O wa sun igbẹjọ ọhun si ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ.