Audu Ogbeh: Mínísítà fẹ́tò ọ̀gbìn ní pápánu Pizza ìlú London làwọn kan ń jẹ ní Nàìjíríà

Ipapanu Pizza Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ijọba apapọ orilẹede NAijiria lọpọ igba ti pariwo pe bi awọn eeyan ṣe n ko ọja wọ orileede naa lati oke okun yoo ṣe akoba fun ọrọ aje rẹ

Laipẹ yii ni minisita fun eto ọgbin lorilẹede Naijiria fọ igba yangan lori pe awọn eeyan kan wa lorilẹede Naijiria to jẹ wi pe ipapanu ti wọn njẹ, lati ilẹ okeere lo ti n wa.

Minisita feto ọgbin, Audu sọ de ori wi pe awọn eeyan kan wa lorilẹede Naijiria to jẹ wi pe ipapanu Pizza ti wọn n jẹ, ilẹ Gẹẹsi ni wọn yoo ti raa ti wọn yoo si fi baalu gbe e wa si orilẹede Naijiria ni kutu hai ọjọ keji.

Audu Ogbeh ṣalaye ọrọ yii lasiko to n dahun ibeere niwaju igbimọ tẹẹkoto kan niile aṣofin apapọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ogbeh gbe ọrọ yii kalẹ lati fi pariwo ọwọja bi awọn eeyan ṣe n ko nnkan wọle sorilẹede Naijiria sita ni.

''$18 miliọnu ni a n na sori itayin, irinwo miliọnu dọla lori rira iyẹfun tomato wole sorilẹede Naijiria. Apẹrẹ rẹ ko si ju ẹgbẹrun meji Naijiria lọ lorilẹede Naijiria."

O tun sọọ siwaju sii pe, "awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan a tilẹ tun maa fi ẹrọ ibanisọrọ wọn ra ipapanu pizza lati ilu London."

Idi niyi ti BBC News Yoruba fi wa gbe gege le lati mọ iye gan ni o lee na eniyan lati ra ipapanu Pizza wa lati oke okun ti ko fẹ fi raa lorilẹede Naijiria.

Lati ra ipapanu Pizza ni oke okun, iyẹn ni ilu London, iye rẹ wa laaarin pọun mẹsan an (£9) si ogun pọoun (£20). Eyi tumọ si pe ni owo naira, iye rẹ yoo jẹ laaarin ẹgbẹrun mẹrin o le diẹ naira (4,224.53) si ẹgbẹrun mẹsan o le diẹ naira (N9,387.39) fun ẹyọ kan.

Ki a kuro nibẹ lọ si iye gan an ni owo baluu ti yoo ba wa si orilẹede Naijiria bayii lati ilu London ni ilẹ Gẹẹsi.

Owo ọkọ wa laaarin ọọdunrun pọun si ẹẹdẹgbẹrun o din aadọta pọun.

Bi a ba ṣi eyi si owo Naira ti orilẹede Naijiria, owo irinna baluu ọhun jẹ laaarin ẹgbẹrun lọna ogoje naira (N140,847.16) ẹgbẹrun mọkandinnirinwo naira (399,036.40) fun irinna baluu ti yoo gbe ipapanu yii wa.

Image copyright @AuduOgbeh
Àkọlé àwòrán Ọrọ Minisita Audu Ogbeh ti fa ọpọ ariyanjiyan laaarin awọn ọmọ Naijiria

Apapọ gbogbo owo yii yoo jẹ laarin ẹgbẹrun lọna aadọja naira si ẹgbẹrun lọna irinwo o le diẹ naira.

Iṣiro yii wa fun ẹyọ ipapanu Pizza kan ṣoṣo.

Bi o ba rii bẹẹ, elo gan an ni iye rẹ lorilẹede Naijiria?

Iye ti wọn n ta ipapanu Pizza lorilẹede Naijiria wa laaarin ẹgbẹrun meji naira si ẹgbẹrun mẹrin naira.

Ka tilẹ wa sọ pe pẹlu owo ọkọ, ki iyẹn jẹ ẹgbẹrun marun. Gbogbo rẹ yoo ku si bii ẹgbẹrun mẹwa o din diẹ naira lati jẹ Pizza ti ko yatọ si ti ilẹ gẹẹsi lorilẹede Naijiria.

Ibeere nla lori ọrọ yii wa ni pe, Ki gan lo wa faa ti awọn eeyan kan fi n fi ipapanu Pizza to wa larọwọto wọn lorilẹede Naijiria silẹ lọ maa wa ti ilu ọba kiri?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLagosollapsedbuilding: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Eko ní ìjọba, aráàlú lọ́wọ́ nínú bí ilé ṣe ń wó