April Fool's Day: Wo àwọn ẹ̀tàn tí àwọn ènìyàn ti ṣe

April fool Image copyright WIKIPEDIA
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ Kíní, Osù Kẹ́rin, ọdọọdún ni àyájọ́ Ọjọ́ April Fool tí àwọn ènìyàn tí ma ń tan àwọn ẹlòmíràn.

Ọjọ 'April Fool' kii se ọjọ isinmi amọ ẹgbẹgbẹrun eniyan lagbaye lo máa n sayajọ ọjọ yii lati sọ nkankan tabi ominiran nipa bi April Fool se bẹrẹ ni agbaye.

Ọjọ Kini, Osu Kẹrin ọdọọdun ni ayajọ ọjọ April Fool ni awọn eniyan ya sọtọ lati maa tan awọn ẹlomiran jẹ.

Ọpọlọpọ eniyan lo n sọ orisirisi nipa bi ọjọ naa ṣe bẹrẹ, awọn miran ni Hilaria to jẹ ọjọ ọdun kan ni ilẹ Rome ti wọn ma n ṣe ni ọjọ kẹẹdọgbọn, osu kẹta.

Bakan naa ni awọn kan sọ wi pe lati inu iwe ti Geoffrey Chaucer kọ to pe orukọ rẹ ni Canterbuty Tales ni ayajọ ọjọ itaja naa bẹrẹ.

Wo awọn nkan itanjẹ ti awọn eniyan ti se ni Ọjọ April Fool.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionColorado ni Amẹrika àti odò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!
  • Loni,Ọjọ April Fool ti ọdun yii ni ile isẹ iroyin kan fi lede wi pe agbabọọlu Super Eagles, Alex Iwobi ti kuro ni Arsenal lọ si Barcelona.
  • Ọjọ April Fool ni ọdun 1989 ni ile isẹ iroyin BBC gbe e jade loju aworan lasiko ti wọn n ka iroyin ere idaraya, ti awọn osisẹ akọrọyin si bẹrẹ si ni ja ninu aworan naa, amọ irọ lasan pẹlu itanjẹ ni.
  • Bakan naa ni awọn eniyan kan ni Ilẹ Gẹẹsi n sọ wi pe wọn ti wọgile bii Ilẹ Gẹẹsi se fẹ kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn si n beere pe ki awọn eniyan mu eleyii to ba jẹ April Fool ninu rẹ.
  • Oju opo imọ ẹrọ Google naa ko gbẹyin ninu itanjẹ Ọjọ April Fool. Wọn fi lede wi pe awọn ti se ẹrọ ti yoo mu ki eniyan ba ewe Tulip sọrọ,ti ewe naa yoo si ma a fun eniyan lesi.
  • Bakan naa ni ile isẹ apanilẹrin ‘Ola’ naa ni awọn ti ni ile igbọnsẹ ni gbogbo ibi. Ohun ti o nilo lati se ni ki eniyan lọ si ori ẹrọ ayelujara wọn lori ẹrọ ilẹwọ wọn, pe ọkọ ile igbọnsẹ yoo de ibi to o wa lẹsẹkẹsẹ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌbádọ́gba nínú ìsèlú àti iṣẹ́ láwùjọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsóké