Kolade Johnson; Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí ọlọ́pàá tó ṣekúpaá

Image copyright Nigeria Police

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko sọ pe ọwọ oun ti tẹ awọn ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o pa ọdọmọkunrin kan nilu Eko.

Ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Aje, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bala Elkana, sọ pe ẹri lati ẹnu awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn lo fun ileeṣẹ ọlọpaa ni anfaani lati da ikọ ọlọpaa to hu iwa ipaniyan naa.

Lọjọ Aiku ni iroyin gba gbogbo ori ayelujara pe awọn ọlọpaa SARS yinbọn pa ọkunrin kan, Kolade Johnson, ni agbegbe Onipẹtẹsi, Mangoro niluu Eko.

'Àwọn SARS ló yìnbọn pa ìyá mi'

SARS já wọ ilé àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ fásitì Akungba

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí SARS

Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn afurasi ọhun ti wa ni atimọle, ati pe wọn yoo fi iya to tọ jẹ wọn labẹle tabi gbe wọn lọ sile ẹjọ ti iwadi ba fi le fihan pe wọn jẹbi ẹsun naa.