Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin

Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin

Aṣà igbeyawo nilẹ Yoruba ni igbesẹ oriṣiiriṣii to n mu ayọ wọnu igbeyawo.

Lẹyin ti ọkọ ati aya ba ti rira tan ni alarinna ti bẹrẹ iṣẹ. Kete ti ọkọ ba ti mọ ojú aya tán ni alarinna a ti yẹba.

Lẹyin eyi ni Mọ̀mí-n-mọ̀ọ́ laarin ẹbi mejeeji kó tó kan ìdána.

Nibi ìdána ni alága iduro fun ẹbi ọkọ ati alaga ijokoo fún ẹbi iyawo a ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii aṣoju fun ẹbi mejeeji.

Awọn obìnrin ni wọn saaba maa n ṣe iṣẹ alaga iduro ati ijokoo nilẹ Yoruba paapaa awọn iyawo ilé.

Ogbeni Ayobami Oladokun jẹ ọdọkunrin ogidi ọmọ Yoruba to yan iṣẹ obinrin laayo gẹgẹ bi alaga iduro ati ijokoo.

O ṣalaye pataki iṣẹ yii fun BBC Yorùbá ati awọn ohun idunnu ati ipenija to rọ mọ ṣiṣe alaga iduro.

Igbeyawo nilẹ Oodua jẹ laarin ẹbi ọkọ ati aya ni eyi ti ikọsilẹ ko fi ki n wọpọ nitori gbogbo ẹbi a fẹ ki igbeyawo naa ni ayọ.

Ayobami Oladokun sọrọ lori ayipada ti oun fẹ ko ba iṣẹ alaga iduro bii ki awọn alaga ma maa gba asiko awọn oninawo pupọ ati pe ki wọn ma maa mu nkan ti kii ṣe ti wọn loju agbo.

Ayobami fi ayo rẹ han lori yiyan iṣẹ yii laayo pe o n mu iwuri ba oun nigba gbogbo.