Offa Robbery: Àwọn aráàlú ṣì n gbé nínú ìpaya lẹ́yìn ọdún kan

Offa Robbery: Àwọn aráàlú ṣì n gbé nínú ìpaya lẹ́yìn ọdún kan

Ọjọ naa re e bi ana ti ariwo sọ niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, nitori iṣẹ awọn adigunjale to yabo ilu naa lọsan gan-gan.

Oni, ọjọ Karun oṣu Kẹrin ọdun 2019 gan an lo pe ọdun kan geerege ti awọn adigunjale yabo ilu Ọffa, ti wọn si ja ileefowopamọ maarun ọtọọtọ lole.

Awọn ole bi ọgbọn niroyin sọ pe o ya wọ ilu naa, ti wọn si di awọn ọna kan pa ninu ilu ki wọn o to wọ awọn ileefowopamọ naa.

Awọn kan lara wọn wọ agọ ọlọpaa to wa nitosi, ti wọn si pa ọlọpaa mẹsan, to fi mọ ọlọpaa obinrin kan to loyun sinu.

Ole nikan kọ ni wọn ja, wọn tun ṣekupa awọn araalu atawọn ọlọpaa. Bakan naa ni awọn kan tun fi ara pa.

Lẹyin ọjọ diẹ ti iṣẹlẹ alagbara naa waye ni ileesẹ ọlọpaa kede pe ọwọ titẹ awọn afurasi meje nipa iranlọwọ fidio ati aworan ti ẹrọ ayaworan to n bẹ ninu ọgba ileefowopamọ ka silẹ.

Igbẹjọ ṣi n lọ lori ẹsun ti wọn fikan awọn afurasi naa di bi a ṣe n sọrọ yi.

Amọ ṣaa, ipo wo ni iṣẹlẹ buruku naa fi ilu Ọffa si?

Awọn to padanu mọlẹbi wọn sinu rẹ n kọ?

Nibo ni nkan de duro lati dena iru iṣẹlẹ bẹ ẹ lọjọ iwaju?

Ẹkunrẹrẹ re e ninu fidio ti BBC Yoruba mu bọ lati ilu Ọffa.