Kìnìhún joko jẹ ẹran ara afurásí ọdẹ tí kò gbààyè kó tó ṣọdẹ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oloola iju pa Ajanaku to pa ode inu igbo

Bi irin ba ko irin, ọkan maa tẹ fun ikeji ni.

Ofin to n ṣe idajọ ẹ̀san fun abẹ̀mí gbogbo ni awọn eeyan gba pé o ṣẹlẹ ninu igbo Kruger National Park ni orilẹ-ede South Africa.

Ninu igbo iṣọdẹ-gbafẹ Kruger National Park ni erin ti ṣèṣì tẹ ọkunrin ọdẹ kan pa lọjọ Iṣẹgun ni eyi ti awọn oṣiṣẹ ibẹ fura si pe o dabi pe ko gbaaye to yeẹ kó gbà ki o to lọ ṣọdẹ nibẹ.

Ni kete ti erin kan ti wọn gba pé o ṣẹṣi tẹ ọkunrin ọdẹ naa pa ṣe kọja siwaju ni wọn ni awọn kinihun yabo ẹran ara ọkunrin naa ti wọn dẹ fi jẹ.

Awọn afurasi ọdẹ ẹgbẹ rẹ ṣalaye fawọn mọlẹbi ọkunrin naa pé bi erin ṣe tẹẹ nibi ti awọn ti n ṣọdẹ ni àwọn kinihun kan yabo awọn ti wọn si jẹ ẹran ara ẹ.

Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn gbiyanju lati wa ẹran ara rẹ to ku ki wọn to ri egungun agbari ọkunrin naa ati ṣokoto to wọ lọjọ Alamisi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJawahir Roble:Hijab tí mò n lò kó jẹ́ kọ́kọ́ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn agbábọ́ọ̀lù mi

Alakoso igbo igbafẹ naa ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun pé o bani ninujẹ gidi ni ati pe ọpọ igba ni awọn maa n kilọ fawọn ero pé igbo naa lewu fun ẹni ti ko ba gbọn ninu gbọn lode.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Bakan naa lo fi kun un pé ijọba ti fi ofin de wiwọ igbo naa lọ ṣodẹ laigba aṣẹ nitori iru iṣẹlẹ bawọn yii.

O mẹnuba awọn idojukọ to n koju igbo Kruger National Park ati ipa ti ijọba orilẹ-ede South Africa n ko lasiko yii lati wa ojutu sii.

Idiyele owo ti wọn n ta ìwo Túùkú fawọn orilẹ ede Asia ni \awọn kan gba pé o ṣokunfa ki ọpọ maa fi ẹmi wọn sinu ewu lati wa ìwo èranko ti wọn maa tà.

Lọjọ Abamẹta to kọja yii ni awọn alaṣẹ papakọ ofurufu Hong Kong gbẹsẹle apoti nla to kun fun ìwo Tuuku towo rẹ to miliọnu meji o le owo dọla ilẹ Amerika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOjojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda