Sudan Protest: Ìkọlùkọgbà bẹ́ sílẹ̀ láàrín àwọn ológún

Orilẹede Sudan

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Orilẹede Sudan

Awọn ọmọ ogun lọ da aabo bo awọn ẹgbẹ kan to n fẹhonu han ni Khartoum eyi to ja si iṣẹlẹ aburu laarin awọn ọmọ ogun atawọn afẹhonu han.

Se lawọn sọja n tiraka lati le awọn ọkọ nla to n tu afẹfẹ taju taju sita lalẹ ọjọ keji ti iwọde wọn latari pe wọn f ki aarẹ Omar al- Bashir kọwe fipo silẹ.

Bẹẹ lawọn ajijagbara ba sa asala ti wọn si wa ibi isadi lọ si bareke awọn ọmọ ogun oju omi ni ibẹru bojo ba walẹ wọọ.

Lara awọn afẹhonu han meje ni wọn ti pa bayii lati ọjọ abamẹta to kọja ti ikọlukọgba yii ti bẹrẹ.

Ọgbẹni Bashir ti wa lori alefa gẹg bi aarẹ fun o ti fẹrẹẹ to ọgbọn ọdun bayii, lati igba naa lo si ti n kọjalẹ lati faye gba gbigbe agbara le ijọba mii lọwọ.

Àkọlé fídíò,

'Celestine fa adá yọ, ó sì gé orí ọmọ mi méjì'

Bayii lo ṣe ṣẹlẹ lọjọ abamẹta

Ọkan lara awọn afẹhonu han sọ fun BBC pe awọn ọkọ ajagbe nla ṣi wọle ti wọn si bẹrẹ si ni fi afẹfẹ tajutaju ati ibọn si awọn ti wọn ṣe ifẹhonu han ni olu ilu orilẹede Sudan.

o ni awn ologun kọkọ pa kẹ́kẹ́ nigba to ya ni wọn gbiyanju lati le awọn oṣiṣẹ alaabo naa lọ.

Awọn to ṣoju wọn koro ni ṣe lawọn oṣiṣẹ alaabo yii tun tunraki lẹẹkeji ti wọn doju kọ wọn ni awọn ba sa lọ si bareke awn ọmọ ogun oju omi lati fara pamọ fun ikọlu wọn to n pẹ.

Àkọlé fídíò,

Ayekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Ali Ibrahim ti Sudanese Professionals Association (SPA) ẹni to ṣe agbatẹru ifẹhonu han naa sọ fun ile iṣẹ iroyin EFE pe ikọ ogun n yinbọn sinu afẹfẹ lati di awọn oṣiṣẹ alaabo ọhun lọwọọ titu awọn ka nibi ifẹhonu han to n waye ni ita olu ile iṣ ogun.

Idi ti awọn ologun fi yi ibi ifẹhonu han naa ka ko ṣi tii ye.