Hakeem: Idán inú eré sinimá ti gbàràdá ní Nàìjíríà

Hakeem: Idán inú eré sinimá ti gbàràdá ní Nàìjíríà

Hakeem Onilogbo to jẹ gbajugbaja apidan lori sinima ni òun ti wa lẹnu iṣe yii lọjọ tó ti pẹ.

Opọlọpọ oṣiṣẹ lo maa n fọwọsowọpọ ki eré sinima to di odindin.

Yatọ si oṣere, a ni oludari, aṣaraloge, abaniwale, agbohunsilẹ, oni ina mọnamọna, ato itage, ọlọ́wọ́ idan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ to sẹ pataki ninu sinima ṣugbọn ti kii ṣe oṣere ni Hakeem Effect to n fi awọn oṣere pa idan to ba wuu.

Opọ arugbo ni Hakeem ti sọ di ọmọge bẹẹ lo ti sọ ẹya ara awọn eeyan di nkan mii laarin ọdun mejila ti oun ti n ṣe.

Hakeem ṣalaye fun BBC Yoruba pé idán lásán ni ṣugbọn ọpọ rẹ n bani lẹru.

O sọrọ lori afojusun rẹ lati di alafo to wa laarin awọn oṣiṣẹ ọlọwọ idan ninu sinima ilu oyinbo ati ti ilẹ Adulawọ.