Manchester United vs Barcelona: Gbajúgbajà apanilẹ́rín, Wòlíì Àrólé ní ìrètí ṣì wà fún Man United ní Camp Nou

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWolii Arole

Kii ṣe iroyin mọ pe ikọ manchester United fi idirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Barcelona ninu idije Champions league, amọṣa bi ọkọọkan awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe n gba iroyin yii sara lo ṣe ọtọọtọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara awọn ololufẹ Manchester United to jẹ ilumọọka lorilẹede Naijiria ni Oluwatoyin Bayegun ti ọpọ mọ si 'Wolii Arole'

Ninu ọrọ to ba BBC news Yoruba sọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa, wolii arole ni ọpẹlọpẹ adura oun gẹgẹ bii wolii ni ko jẹ ki iye paṣan ti Manchester United jẹ lọwọ Barcelona o pọ pupọ ju ẹyọ kan lọ.

Wolii arole ni abajade ifẹsẹwọnsẹ naa ba oun ninu jẹ pupọ ṣugbọn ireti ko tii pin.

O ni ko si nnkan ti ko lee ṣẹlẹ ni papa iṣire Camp Nou lorilẹde Spain nigba ti wọn ba lọ pade fun ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa.

Barca na Manchester United pẹu ami ayo kan si odo ni ọjọru.