Segalink: ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró; bẹ́ẹ̀, wọn kò ni agbẹnusọ

Segalink: ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró; bẹ́ẹ̀, wọn kò ni agbẹnusọ

Gbajugbaja amofin Segun Awosanya wa ojútùú siṣoro ki awọn agbofinro maa yinbọn pa alaiṣẹ ara ilu'Àwọn SARS ló yìnbọn pa ìyá mi'.

Ninu itan Naijiria, ọpọlọpọ lo gba pe asiko yii SARS já wọ ilé àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ fásitì Akungba ni awọn agbofinro ti ṣe iku pa alaiṣe julọ ni eyi ti wọn pe ni àṣìta ìbọn ni ọpọ igbaỌlọ́pàá gbé àwọn tó yìnbọn lu olólùfẹ́ ní Ajegunle .

Lọwọlọwọ ni awọn eniyan Naijiria n pariwo ninu iwọde kaakiri pe ki ijọba fofin de awọn ọlọpaa kogberegbe SARS ati pe ki atunto wọ igbesẹ bi ọlọpaa ṣe n yinbọn ni aarin iluÌgbà wo ni àjọ ọ́lọ́pàá yóò káwọ́ SARS?.

Ọkan pataki lara awọn amofin to n pariwo lori ẹrọ ayelujara pe ki ijọba wa nkan ṣe si ọrọ awọn agbofinroArá ìlú túbọ̀ ń polongo ìfòpin sí SARS paapaa awọn SARS ni Amofin Segun Awosanya to jẹ alakoso #END SARS.

Amofin ti ọpọlọpọ mọ si Sega L'évailleur loju òpó twitter ati Segalink ṣalaye fun BBC Yoruba pé adiyẹ awọn ọlọpaa naa n laagun, ṣugbọn ìyẹ́ ni kò jẹ ki a mọỌwọ́ tẹ afurasí méjì tó nííṣe pẹ̀lú ìjínígbe Ọgá panápaná l'Eko.

O ni iṣẹ ọlọpaa ko faaye gba iwọde kotẹmilọrun rara, koda nigba ti iya owo oṣù ati ajẹmọnu ba n jẹ wọn.

Sega link mẹnuba awọn igbesẹ to yẹ ki ijọba gbe lati di àlàfo to wa laarin awọn agbofinro ati ara ìlú.

O ni ti ijọba ba tẹ awọn agbofinro lọrun, wọn ko ni ṣaa dede maa yinbọn pa alaiṣẹ tabi ki wọn maa gba owo aitọ lọwọ awọn ara ilu.